56:1
Nígbà tí Ìṣẹ̀lẹ̀ (Àjíǹde) bá ṣẹlẹ̀,
56:2
- kò sí irọ́ kan nípa ìṣẹ̀lẹ̀ rẹ̀-
56:3
ó máa mú (àwọn kan) wálẹ̀ (sínú Iná), ó sì máa gbé (àwọn kan) sókè (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra).
56:4
Nígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní mímìtìtì,
56:5
àti nígbà tí Wọ́n bá fọ́ àwọn àpáta ní fífọ́ wómúwómú,
56:6
- wọ́n sì máa di eruku àfẹ́dànù -
56:7
ẹ̀yin sì máa jẹ́ oríṣi mẹ́ta.[1]
56:8
Àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún, kí ni (ó máa ti dára tó fún) àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún?
56:9
Àwọn èrò ọwọ́ òsì, kí ni (ó máa ti burú tó fún) àwọn èrò ọwọ́ òsì?
56:10
Àwọn aṣíwájú sì ni àwọn aṣíwájú.
56:11
Àwọn wọ̀nyẹn ni alásùn-únmọ́ (Allāhu)
56:12
nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.
56:13
Wọ́n pọ̀ nínú àwọn ẹni àkọ́kọ́.
56:14
Wọ́n sì kéré nínú àwọn ẹni Ìkẹ́yìn.
56:15
(Wọn yóò wà) lórí ìtẹ́ tí wọ́n fi góòlù hun.
56:16
Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú sórí rẹ̀, wọn sì máa dojú kọra wọn.
56:17
Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí kò níí darúgbó yó sì máa lọ bọ̀ láààrin wọn
56:18
pẹ̀lú àwọn ife omi, ohun ìrọmi fẹ̀ǹfẹ̀ àti ife ọtí aládùn láti inú odò kan tó ń ṣàn (káà kiri ọ̀dọ̀ wọn).
56:19
Kò níí fọ́ wọn lórí; kò sì níí mú wọn húnrìrà.
56:20
Èso tí wọn yóò máa ṣẹ̀ṣà nínú rẹ̀ (tún wà fún wọn).
56:21
Àti ẹran ẹyẹ, èyí tí wọ́n ń fẹ́ (yó wà fún wọn).
56:22
Àwọn obìnrin ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ (tún wà fún wọn).
56:23
Wọ́n dà bí àlúùúlù (òkúta olówó-iye-bíye) tí wọ́n fi pamọ́ sínú apó rẹ̀.
56:24
(Ìwọ̀nyí ni) ẹ̀san fún ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
56:25
Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ àti ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.
56:26
Àyàfi ọ̀rọ̀ àlàáfíà, àlàáfíà.
56:27
Àwọn èrò ọwọ́ ọtún, kí ni (ó máa ti dára tó fún) àwọn èrò ọwọ́ ọtún?
56:28
(Wọn yóò wà) ní ìdí igi tí kò ní ẹ̀gún,
56:29
àti ọ̀gẹ̀dẹ̀ tó so jìgbìnnì,
56:30
àti ibòji tó gbòòrò,
56:31
àti omi tó ń ṣàn láì dáwọ́ dúró,
56:32
àti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ èso,
56:33
tí kò níí já (ní ọ̀dọ̀ wọn), kò sì níí dèèwọ̀ (fún wọn).
56:34
(Wọ́n máa wà lórí) ìtẹ́ tí wọ́n gbé sókè.
56:35
Dájúdájú Àwa dá (àwọn obìnrin Ọgbà Ìdẹ̀ra) ní ẹ̀dá kan (tó yàtọ̀ sí tayé).
56:36
A sì ṣe wọ́n ní wúńdíá,
56:37
olólùfẹ́ ọkọ. Wọ́n sì dọ́gba ní ọjọ́ orí.
56:38
(Wọ́n wà) fún àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún.
56:39
Wọ́n pọ̀ nínú àwọn ẹni àkọ́kọ́.
56:40
Wọ́n tún pọ̀ nínú àwọn ẹni Ìkẹ́yìn.[1]
56:41
Àwọn èrò ọwọ́ òsì, kí ni (ó máa ti burú tó fún) àwọn èrò ọwọ́ òsì?
56:42
(Wọn yóò wà) nínú atẹ́gùn gbígbóná (iná) àti omi tó gbóná parí,
56:43
àti ní abẹ́ ibòji eléèéfín dúdú,
56:44
kò tutù, kò sì dára.
56:45
Dájúdájú wọ́n ti jẹ́ onígbẹdẹmukẹ ṣíwájú ìyẹn.
56:46
Wọ́n sì máa ń ṣoríkunkun lórí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.
56:47
Wọ́n sì máa ń wí pé: “Ṣé nígbà tí a bá di òkú, tí a sì di erùpẹ̀ àti egungun, ǹjẹ́ Wọn yóò tún gbé wa dìde ni?
56:48
Ṣé àti àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́?”
56:49
Sọ pé: “Dájúdájú àwọn ẹni àkọ́kọ́ àti àwọn ẹni Ìkẹ́yìn,
56:50
dájúdájú A óò kó wọn jọ papọ̀ ní àkókò ọjọ́ kan tí A ti mọ̀.”
56:51
Lẹ́yìn náà, dájúdájú ẹ̀yin olùṣìnà, olùpe-òdodo-nírọ́,
56:52
dájúdájú ẹ̀yin máa jẹ nínú igi zaƙƙūm (igi iwọ).
56:53
Ikùn yín sì máa kún bámúbámú fún (jíjẹ) igi náà.
56:54
Ẹ̀yin yó sì máa mu omi tó gbóná parí lé e lórí.
56:55
Ẹ̀yin yóò máa mu ún ní ìmumi ràkúnmí tí òǹgbẹ ń gbẹ.
56:56
Èyí ni n̄ǹkan àlejò wọn ní Ọjọ́ ẹ̀san.
56:57
Àwa l’A ṣẹ̀dá yín. Kí ni kò jẹ́ kí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo!
56:58
Ẹ sọ fún Mi nípa àtọ̀ tí ẹ̀ ń dà jáde (sínú àpòlùkẹ́),
56:59
ṣé ẹ̀yin lẹ ṣẹ̀dá rẹ̀ ni tàbí Àwa l’A ṣẹ̀dá rẹ̀?
56:60
Àwa l’A yan kádàrá (ọjọ́) ikú fún gbogbo yín. Kò sì sí ẹni tó lè dá Wa lágara
56:61
láti yí irú yín padà (láti inú erùpẹ̀ sí alààyè), kí á sì ṣẹ̀dá yín (ní ọ̀tun) sínú ohun tí ẹ kò mọ̀ (nínú àwọn ìrísí).
56:62
Ẹ kúkú mọ ìṣẹ̀dá àkọ́kọ́ (pé láti ibi àìsí ni ẹ ti di alààyè), ẹ kò ṣe lo ìrántí?
56:63
Ẹ sọ fún Mi nípa n̄ǹkan tí ẹ̀ ń gbìn sínú ilẹ̀,
56:64
ṣé ẹ̀yin l’ẹ̀ ń jẹ́ kí ó hù jáde tàbí Àwa l’À ń jẹ́ kí ó hù jáde?
56:65
Tí A bá fẹ́ ni, Àwa ìbá sọ ọ́ di gbígbẹ, ẹ̀yin yó sì máa ṣèèmọ̀ (tí ẹ óò máa ká àbámọ̀).
56:66
(Ẹ̀yin yó sì wí pé:) “Dájúdájú àwa ti di onígbèsè.”
56:67
(Àwọn mìíràn yó sì wí pé:) “Rárá o! Wọ́n ṣe ìkórè oko ní èèwọ̀ fún wa ni.”
56:68
Ẹ sọ fún mi nípa omi tí ẹ̀ ń mu,
56:69
ṣé ẹ̀yin l’ẹ̀ ń sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti inú ẹ̀ṣújò ni tàbí Àwa l’À ń sọ̀ ọ́ kalẹ̀?
56:70
Tí A bá fẹ́ ni, Àwa ìbá ṣe é ní omi tó móró. Ẹ ò ṣe máa dúpẹ́?
56:71
Ẹ sọ fún Mi nípa iná tí ẹ̀ ń dá,
56:72
ṣé ẹ̀yin l’ẹ ṣẹ̀dá igi rẹ̀ ni tàbí Àwa ni Aṣẹ̀dá?
56:73
Àwa ṣe iná ayé ní ìrántí (fún Iná ọ̀run) àti n̄ǹkan èlò fún àwọn onírìn-àjò.
56:74
Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi.
56:75
Nítorí náà, Mò ń fi àwọn àyè tí ìkọ̀ọ̀kan gbólóhùn al-Ƙur’ān wà nínú sánmọ̀ búra.[1]
56:76
Dájúdájú ìbúra ńlá ni, tí ẹ bá mọ̀.
56:77
Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni n̄ǹkan kíké alápọ̀n-ọ́nlé.
56:78
Ó wà nínú Tírà kan tí wọ́n ń fi ààbò bò (ìyẹn Laohul-Mahfūṭḥ).
56:79
Kò sí ẹni tó lè fọwọ́ kàn án (ní ọ̀dọ̀ Allāhu) àfi àwọn ẹni mímọ́ (ìyẹn, àwọn mọlāika).
56:80
Wọ́n sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
56:81
Nítorí náà, ṣé ọ̀rọ̀ (al-Ƙur’ān) yìí l’ẹ̀ ń pè ní irọ́?
56:82
Ẹ sì ń sọ ìdúpẹ́ arísìkí yín di pé dájúdájú ẹ̀ ń pe òdodo ní irọ́.[1]
56:83
Kí ni ó máa ti rí (fún yín) nígbà tí ẹ̀mí (yín) bá dé ọ̀nà ọ̀fun,
56:84
tí ẹ̀yin yó sì máa wò bọ̀ọ̀ nígbà yẹn?
56:85
Àwa sì súnmọ́ ọn ju ẹ̀yin lọ, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò ríran.[1]
56:86
Ẹ̀yin kò ṣe jẹ́ ẹni tí A ò níí gbẹ̀san lára rẹ̀,
56:87
kí ẹ sì dá (ẹ̀mí tí ó fẹ́ bọ́) padà, tí ẹ bá jẹ́ olódodo.
56:88
Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn alásùn-únmọ́ (Wa),
56:89
ìsinmi, èsè tó dára àti Ọgbà Ìdẹ̀ra (ni tirẹ̀).
56:90
Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún,
56:91
àlàáfíà ni fún ọ láààrin àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún.
56:92
Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn olùpe-òdodo-nírọ́, àwọn olùṣìnà,
56:93
n̄ǹkan àlejò (wọn) ni omi tó gbóná parí
56:94
àti wíwọ inú iná Jẹhīm.
56:95
Dájúdájú èyí, òhun ni òdodo tó dájú.
56:96
Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi.