44:1
Hā mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1]
44:2
(Allāhu) fi Tírà tó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá búra.
44:3
Dájúdájú Àwa sọ̀ ọ́ kalẹ̀ nínú òru ìbùkún.[1] Dájúdájú Àwa ń jẹ́ Olùkìlọ̀.
44:4
Nínú òru náà ni wọ́n ti máa yanjú gbogbo ọ̀rọ̀ tí kò níí tàsé (lórí ẹ̀dá).
44:5
Àṣẹ kan ni láti ọ̀dọ̀ Wa. Dájúdájú Àwa l’À ń rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́.
44:6
Ìkẹ́ kan ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
44:7
Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin méjèèjì tí ẹ̀yin bá jẹ́ alámọ̀dájú.
44:8
Kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́.
44:9
Síbẹ̀, wọ́n sì wà nínú iyèméjì, tí wọ́n ń ṣeré.
44:10
Nítorí náà, máa retí ọjọ́ tí sánmọ̀ yóò mú èéfín pọ́nńbélé wá.
44:11
Ó máa bo àwọn ènìyàn mọ́lẹ̀. Èyí ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
44:12
(Àwọn ènìyàn yóò wí pé): Olúwa wa, gbé ìyà náà kúrò fún wa, dájúdájú àwa yóò gbàgbọ́ ní òdodo.
44:13
Báwo ni ìrántí ṣe lè wúlò fún wọn (lásìkò ìyà)? Òjíṣẹ́ pọ́nńbélé kúkú ti dé bá wọn.
44:14
náà, wọ́n gbúnrí kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀. Wọ́n sì wí pé: “Wèrè tí àwọn ènìyàn kan ń kọ́ ní ẹ̀kọ́ ni.”
44:15
Dájúdájú Àwa máa gbé ìyà náà kúrò fún ìgbà díẹ̀. Dájúdájú ẹ̀yin yóò tún padà (sínú àìgbàgbọ́).
44:16
Ọjọ́ tí A óò gbá (wọn mú) ní ìgbámú tó tóbi jùlọ; dájúdájú Àwa yóò gba ẹ̀san ìyà (lára wọn).
44:17
Dájúdájú A dán àwọn ènìyàn Fir‘aon wò ṣíwájú wọn. Òjíṣẹ́ alápọ̀n-ọ́nlé sì dé wá bá wọn.
44:18
(Ó sọ pé): “Ẹ kó àwọn ẹrúsìn Allāhu lé mi lọ́wọ́. Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín.
44:19
Ẹ má ṣe ṣègbéraga sí Allāhu. Dájúdájú èmi ti mú ẹ̀rí pọ́nńbélé wá ba yín.
44:20
Dájúdájú Èmi sá di Olúwa mi àti Olúwa yín pé kí ẹ má ṣe sọ mí ní òkò.
44:21
Tí ẹ kò bá sì gbà mí gbọ́, ẹ fi mí sílẹ̀ jẹ́.”
44:22
Nítorí náà, ó pe Olúwa rẹ̀ pé dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni ìjọ ẹlẹ́sẹ̀.
44:23
(Allāhu sọ pé): “Mú àwọn ẹrúsìn Mi rìn ní alẹ́ (nítorí pé) wọn yóò tọ̀ yín lẹ́yìn.
44:24
Kí o sì fi agbami òkun náà sílẹ̀ (ná) kí ó dákẹ́ rọ́rọ́ láì níí ru (kí ojú ọ̀nà tí ẹ tọ̀ nínú rẹ̀ lè wà bẹ́ẹ̀, kí Fir‘aon àti ọmọ-ogun rẹ̀ lè kó sójú-ọ̀nà náà). Dájúdájú àwọn ni ọmọ ogun tí A máa tẹ̀rì sínú rẹ̀.
44:25
Mélòó mélòó nínú àwọn ọgbà oko àti odò ìṣẹ́lẹ̀rú tí wọ́n fi sílẹ̀ (lẹ́yìn ìparun wọn).
44:26
Àti àwọn irúgbìn pẹ̀lú àyè àpọ́nlé (tí wọ́n fi sílẹ̀).
44:27
Àti ìdẹ̀ra tí wọ́n ń gbádùn nínú rẹ̀ (ṣíwájú ìparun wọn).
44:28
Báyẹn (ni ọ̀rọ̀ wọn ṣe rí). A sì jogún (ìlú) wọ́n fún ìjọ ènìyàn mìíràn.
44:29
Nígbà náà, sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò sunkún wọn. Wọn kò sì fi ìyà wọn falẹ̀.
44:30
Dájúdájú A gba àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl là nínú ìyà yẹpẹrẹ.
44:31
(A là wọ́n) lọ́wọ́ Fir‘aon. Dájúdájú ó jẹ́ onígbèéraga. Ó sì wà nínú àwọn alákọyọ.
44:32
A kúkú ṣà wọ́n lẹ́ṣà lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò tiwọn) pẹ̀lú ìmọ̀ (tí a mọ̀ nípa wọn).[1]
44:33
A sì fún wọn ní àwọn àmì tí àdánwò pọ́nńbélé wà nínú rẹ̀.
44:34
Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ń wí pé:
44:35
“Kò sí ikú kan àyàfi ikú àkọ́kọ́ (tí ó pa wá nílé ayé). Wọn kò sì níí gbé wa dìde.
44:36
(Bí bẹ́ẹ̀ kọ́), ẹ mú àwọn bàbá wa wá tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”
44:37
Ṣé àwọn ni wọ́n lóore jùlọ ni tàbí àwọn ènìyàn Tubba‘u àti àwọn tó ṣíwájú wọn? A pa wọ́n rẹ́; dájúdájú wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀.
44:38
A kò ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin méjèèjì pẹ̀lú eré ṣíṣe.
44:39
A kò dá àwọn méjèèjì bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.
44:40
Dájúdájú ọjọ́ òpínyà (ìyẹn, ọjọ́ àjíǹde) ni àkókò àdéhùn fún gbogbo wọn pátápátá.
44:41
Ní ọjọ́ tí ọ̀rẹ́ kan kò níí fi kiní kan rọ ọ̀rẹ́ kan lọ́rọ̀. A kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.
44:42
Àyàfi ẹni tí Allāhu bá kẹ́. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
44:43
Dájúdájú igi zaƙūm
44:44
ni oúnjẹ ẹlẹ́ṣẹ̀.
44:45
Ó dà bí ògéré epo gbígbóná tí ń hó nínú ikùn
44:46
(tó) dà bí híhó omi tó gbóná gan-an.
44:47
Ẹ mú un. Kí ẹ wọ́ ọ sáàrin gbùngbùn inú iná Jẹhīm.
44:48
Lẹ́yìn náà, ẹ rọ́ ìyà olómi gbígbóná lé e lórí.
44:49
Tọ́ ọ wò (ṣebí) dájúdájú ìwọ ni alágbára, alápọ̀n-ọ́nlé (gẹ́gẹ́ bí ó ṣe pe ara rẹ).
44:50
Dájúdájú (ìyà) èyí ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń ṣeyèméjì nípa rẹ̀!
44:51
Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù Allāhu yóò wà ní àyè ìfàyàbalẹ̀.
44:52
(Wọn yóò wà) nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra pẹ̀lú àwọn omi ìṣẹ́lẹ̀rú (ní ìsàlẹ̀ rẹ̀).
44:53
Wọn yóò máa wọ aṣọ àrán fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ àti àrán tó nípọn; wọn yó sì máà kọjú síra wọn (sọ̀rọ̀).
44:54
Báyẹn (ni ọ̀rọ̀ wọn yó ṣe rí). A sì máa fi àwọn obìnrin ẹlẹ́yinjú-ẹgẹ́ ṣe ìyàwó fún wọn.
44:55
Wọn yóò máa bèèrè fún gbogbo n̄ǹkan eléso nínú (Ọgbà Ìdẹ̀ra) lẹ́ni ìfàyàbalẹ̀.
44:56
Wọn kò níí tọ́ ikú wò níbẹ̀ àyàfi ikú àkọ́kọ́ (tí wọ́n ti kú nílé ayé). (Allāhu) sì máa ṣọ́ wọn níbi ìyà iná Jẹhīm.
44:57
Ó jẹ́ oore àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Ìyẹn ni èrèǹjẹ ńlá.
44:58
Nítorí náà, dájúdájú A fi èdè abínibí rẹ (èdè Lárúbáwá) ṣe (kíké al-Ƙur’ān àti àgbọ́yé rẹ̀) ní ìrọ̀rùn nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.
44:59
Nítorí náà, máa retí[1]. Dájúdájú àwọn náà ń retí.