al-Mursalat (المُرْسَلَات)

Yoruba:Mikail - Yoruba:Mikail

Chapter 77 • 50 verses • Meccan

← Previous Chapter Next Chapter →
77:1 Allāhu fi àwọn atẹ́gùn tó ń sáré ní tẹ̀léǹtẹ̀lé búra.
77:2 Ó fi àwọn ìjì atẹ́gùn tó ń jà búra.
77:3 Ó fi àwọn atẹ́gùn tó ń tú èṣújò ká búra.
77:4 Ó fi àwọn tó ń ṣèpínyà láààrin òdodo àti irọ́ búra.
77:5 Ó fi àwọn mọlāika tó ń mú ìrántí wá (bá àwọn Òjíṣẹ́) búra.
77:6 (Ìrántí náà jẹ́) àwíjàre tàbí ìkìlọ̀.
77:7 Dájúdájú ohun tí A ṣe ní àdéhùn fún yín kúkú máa ṣẹlẹ̀.
77:8 Nítorí náà, nígbà tí wọ́n bá pa (ìmọ́lẹ̀) ìràwọ̀ rẹ́,
77:9 àti nígbà tí wọ́n bá ṣí sánmọ̀ sílẹ̀ gbagada,
77:10 àti nígbà tí wọ́n bá ku àwọn àpáta dànù,
77:11 àti nígbà tí wọ́n bá fún àwọn Òjíṣẹ́ ní àsìkò láti kójọ (pẹ̀lú ìjọ wọn),
77:12 ọjọ́ wo ni wọ́n so (àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí) rọ̀ fún ná?
77:13 Fún ọjọ́ ìpínyà (láààrin àwọn ẹ̀dá) ni.
77:14 Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ìpínyà?
77:15 Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
77:16 Ǹjẹ́ Àwa kò ti pa àwọn ẹni àkọ́kọ́ rẹ́ bí?
77:17 Lẹ́yìn náà, A sì máa fi àwọn ẹni Ìkẹ́yìn tẹ̀lé wọn (nínú ìparun).
77:18 Báyẹn ni A ó ti ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
77:19 Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
77:20 Ṣé A kò ṣẹ̀dá yin láti inú omi lílẹ yẹpẹrẹ bí?
77:21 Lẹ́yìn náà, A fi sínú àyè ààbò (ìyẹn, ilé-ọmọ)
77:22 títí di gbèdéke àkókò kan tí A ti mọ̀ (ìyen, ọjọ́ ìbímọ).
77:23 A sì ní ìkápá àti àyànmọ́ (lórí rẹ̀. Àwa sì ni) Olùkápá àti Olùpèbùbù ẹ̀dá tó dára.
77:24 Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
77:25 Ǹjẹ́ Àwa kò ṣe ilẹ̀ ní ohun tó ń kó ẹ̀dá jọ mọ́ra wọn;
77:26 (ìyẹn) àwọn alààyè àti àwọn òkú?
77:27 A sì fi àwọn àpáta gbagidi gíga-gíga sínú rẹ̀. A sì fún yín ní omi dídùn mu.
77:28 Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
77:29 Ẹ máa lọ sí ibi tí ẹ̀ ń pè ní irọ́.
77:30 Ẹ máa lọ sí ibi èéfín ẹlẹ́ka mẹ́ta.
77:31 Kì í ṣe ibòji tútù. Kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ìjòfòfò Iná.
77:32 Dájúdájú (Iná náà) yóò máa ju ẹ̀tapàrà (rẹ̀ sókè tó máa dà) bí pẹ̀tẹ́ẹ̀sì.
77:33 (Ó máa dà) bí àwọn ràkúnmí aláwọ̀ omi ọsàn.
77:34 Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́
77:35 Èyí ni ọjọ́ tí wọn kò níí sọ̀rọ̀.
77:36 A kò sì níí yọ̀ǹda (ọ̀rọ̀ sísọ) fún wọn, áḿbọ̀sìbọ́sí pé wọ́n yóò mú àwáwí wá.
77:37 Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
77:38 Èyí ni ọjọ́ ìpínyà. Àwa yó sì kó ẹ̀yin àti àwọn ẹni àkọ́kọ́ jọ.
77:39 Tí ẹ bá ní ète kan lọ́wọ́, ẹ déte sí Mi wò.
77:40 Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
77:41 Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù Allāhu yóò wà níbi ibòji àti àwọn omi ìṣẹ́lẹ̀rú,
77:42 àti àwọn èso èyí tí wọ́n bá ń fẹ́.
77:43 Ẹ jẹ, kí ẹ sì mu pẹ̀lú ìgbádùn nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
77:44 Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
77:45 Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
77:46 Ẹ jẹ, kí ẹ sì gbádùn fún ìgbà díẹ̀. Dájúdájú ẹlẹ́ṣẹ̀ ni yín.
77:47 Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
77:48 Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé kí wọ́n kírun, wọn kò níí kírun.
77:49 Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
77:50 Nígbà náà, ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀?[1]