78:1
Nípa kí ni wọ́n ń bíra wọn léèrè ná?
78:2
Nípa ìró ìkọ̀kọ̀ ńlá ni,
78:3
èyí tí wọ́n ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀.
78:4
Rárá! Wọ́n ń bọ̀ wá mọ̀.
78:5
Lẹ́yìn náà, rárá sẹ́, wọ́n ń bọ̀ wá mọ̀.
78:6
Ǹjẹ́ Àwa kò ṣe ilẹ̀ ní ìtẹ́ bí,
78:7
àti àwọn àpáta ní èèkàn (fún ilẹ̀)?
78:8
A sì ṣẹ̀dá yín ní oríṣiríṣi (akọ àti abo).
78:9
A ṣe oorun yín ní ìsinmi.
78:10
A tún ṣe alẹ́ ní ìbora.
78:11
A tún ṣe ọ̀sán ní (àsìkò fún) wíwá ìjẹ-ìmu.
78:12
A tún mọ sánmọ̀ méje tó lágbára sókè yín.
78:13
A tún ṣe òòrùn ní ìmọ́lẹ̀ tó ń tàn gbòlà.
78:14
Àti pé A sọ omi tó ń bọ́ tẹ̀léra wọn kalẹ̀ láti inú àwọn ẹ̀ṣújò
78:15
nítorí kí Á lè fi mú kóró èso àti irúgbìn jáde
78:16
pẹ̀lú àwọn ọgbà tó kún digbí fún n̄ǹkan oko.
78:17
Dájúdájú ọjọ́ ìpínyà, ó ní gbèdéke àkókò kan.
78:18
(Ìyẹn ni) ọjọ́ tí wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. Ẹ̀yin yó sì máa wá níjọ-níjọ.
78:19
Wọ́n sì máa ṣí sánmọ̀ sílẹ̀. Ó sì máa di àwọn ìlẹ̀kùn.
78:20
Wọ́n máa mú àwọn àpáta rìn (bọ́ sí àyè mìíràn). Ó sì máa di ahúnpeéná.
78:21
Dájúdájú iná Jahanamọ, ó lúgọ sílẹ̀ lójú ọ̀nà.
78:22
(Ó jẹ́) ibùgbé fún àwọn alákọyọ.
78:23
Wọn yóò máa gbé inú rẹ̀ fún ìgbà gbọọrọ.
78:24
Wọn kò níí rí ìtura tàbí ohun mímu kan tọ́wò nínú rẹ̀,
78:25
àyàfi omi tó gbóná parí àti àwọnúwẹ̀jẹ̀.
78:26
(Ó jẹ́) ẹ̀san tó ṣe wẹ́kú (iṣẹ́ wọn).
78:27
Dájúdájú wọn kì í retí ìṣírò-iṣẹ́.
78:28
Wọ́n sì pe àwọn āyah Wa ní irọ́ gan-an.
78:29
Gbogbo n̄ǹkan sì ni A ti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú Tírà kan.
78:30
Nítorí náà, ẹ tọ́ (ìyà) wò. A ò sì níí ṣe àlékún kan fún yín bí kò ṣe ìyà.
78:31
Dájúdájú ìgbàlà wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
78:32
Àwọn ọgbà oko àti èso àjàrà,
78:33
àti àwọn ọlọ́mọge, tí wọn kò júra wọn lọ lọ́jọ́-orí,
78:34
àti ife ọtí tó kún dẹnu (ni ẹ̀san wọn).
78:35
Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ àti ọ̀rọ̀ irọ́ nínú rẹ̀.
78:36
(Ó jẹ́) ẹ̀san láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, (ó sì jẹ́) ọrẹ ní ìbámu sí ìṣírò-iṣẹ́ (wọn).
78:37
(Ẹsan náà wá láti ọ̀dọ̀) Olúwa àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohun tó wà láààrin méjèèjì, Àjọkẹ́-ayé. Wọn kò sì ní ìkápá ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Rẹ̀.
78:38
Ọjọ́ tí mọlāika Jibrīl àti àwọn mọlāika (mìíràn) yóò dúró ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Wọn kò sì níí sọ̀rọ̀ àfi ẹni tí Àjọké-ayé bá yọ̀ǹda fún. Onítọ̀ún sì máa sọ̀rọ̀ tó máa ṣe wẹ́kú.
78:39
Ìyẹn ni ọjọ́ òdodo. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mú ọ̀nà tó máa gbà ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ pọ̀n (ní ti ìronúpìwàdà).
78:40
Dájúdájú A fi ìyà tó súnmọ́ ṣe ìkìlọ̀ fún yín. Ọjọ́ tí ènìyàn yóò máa wo ohun tí ó tì síwájú, aláìgbàgbọ́ yó sì wí pé: “Yéè, èmi ìbá sì jẹ́ erùpẹ̀, (èmi ìbá là nínú ìyà).”