79:1
Allāhu fi àwọn mọlāika tó ń fi ọ̀nà èle gba ẹ̀mí àwọn aláìgbàgbọ́ búra.
79:2
Ó tún fi àwọn mọlāika tó ń fi ọ̀nà ẹ̀rọ̀ gba ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo búra.
79:3
Ó tún fi àwọn mọlāika tó ń yára gágá níbi àṣẹ Rẹ̀ búra.
79:4
Ó tún fi àwọn mọlāika tó máa ṣíwájú ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo wọnú Ọgbà Ìdẹ̀ra tààrà búra.
79:5
Ó tún fi àwọn mọlāika tó ń ṣètò nínú sánmọ̀ àti ilé ayé pẹ̀lú àṣẹ Allāhu búra.
79:6
Ní ọjọ́ tí ìmìtìtì máa mi gbogbo ayé tìtì.[1]
79:7
Ohun tí ó máa tẹ̀lé e máa ṣẹlẹ̀ tẹ̀lé e.[1]
79:8
Àwọn ọkàn yóò máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ ní ọjọ́ yẹn.
79:9
Ojú wọn yó sì wálẹ̀ ní ti ìyẹpẹrẹ.
79:10
Wọn yóò wí pé: “Ṣé Wọ́n tún máa dá wa padà sí ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀mí (bíi tayé ni)?
79:11
Ṣé nígbà tí a ti di eegun tó kẹfun tán?”
79:12
Wọ́n wí pé: “Ìdápadà òfò nìyẹn nígbà náà (fún ẹni tó pè é ní irọ́.)”
79:13
Nítorí náà, igbe ẹyọ kan sì ni.
79:14
Nígbà náà ni wọn yóò bára wọn lórí ilẹ̀ gban̄sasa.
79:15
Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ (Ànábì) Mūsā ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?
79:16
(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ̀ pè é ní àfonúfojì mímọ́, Tuwā.
79:17
Lọ bá Fir‘aon, dájúdájú ó ti tayọ ẹnu-ààlà.
79:18
Kí o sì sọ pé: “Ǹjẹ o máa ṣàfọ̀mọ́ ara rẹ (kúrò nínú àìgbàgbọ́) bí?
79:19
Kí èmi sì fi ọ̀nà mọ̀ ọ́ dé ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, kí o sì páyà (Rẹ̀).”
79:20
Ó sì fi àmì tó tóbi hàn án.
79:21
(Àmọ́) ó pè é ní òpùrọ́. Ó sì yapa (rẹ̀).
79:22
Lẹ́yìn náà, ó kẹ̀yìn sí i. Ó sì ń ṣiṣẹ́ (takò ó).
79:23
Ó kó (àwọn ènìyàn) jọ, ó sì ké gbàjarì.
79:24
Ó sì wí pé: “Èmi ni olúwa yín, ẹni gíga jùlọ.”
79:25
Nítorí náà, Allāhu gbá a mú pẹ̀lú ìyà ìkẹ́yìn àti àkọ́kọ́ (nípa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ ìkẹ́yìn yìí àti àkọ́kọ́).[1]
79:26
Dájúdájú àríwòye wà nínú ìyẹn fún ẹni tó ń páyà (Allāhu).
79:27
Ṣé ẹ̀yin lẹ lágbára jùlọ ní ìṣẹ̀dá ni tàbí sánmọ̀ tí Allāhu mọ?
79:28
Allāhu gbé àjà rẹ̀ ga sókè. Ó sì ṣe é ní pípé tó gún régé.
79:29
Ó ṣe òru rẹ̀ ní dúdú. Ó sì fa ìyálẹ̀ta rẹ̀ yọ jáde.
79:30
Àti ilẹ̀, Ó tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ lẹ́yìn ìyẹn.[1]
79:31
Ó mú omi rẹ̀ àti irúgbìn rẹ̀ jáde láti inú rẹ̀.
79:32
Àti àwọn àpáta, Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ ṣinṣin.
79:33
Ìgbádùn ni fún yín àti fún àwọn ẹran-ọ̀sìn yín.
79:34
Ṣùgbọ́n nígbà tí ìparun ńlá bá dé,
79:35
ní ọjọ́ tí ènìyàn yóò rántí ohun tó ṣe níṣẹ́.
79:36
Wọ́n sì máa fi Iná hàn kedere fún (gbogbo) ẹni tó ríran.
79:37
Nítorí náà, ní ti ẹni tó tayọ ẹnu-ààlà,
79:38
tí ó tún gbé àjùlọ fún ìṣẹ̀mí ayé,
79:39
dájúdájú iná Jẹhīm, òhun ni ibùgbé (rẹ̀).
79:40
Ní ti ẹni tí ó páyà ìdúró níwájú Olúwa rẹ̀, tí ó tún kọ ìfẹ́-inú fún ẹ̀mí (ara rẹ̀),
79:41
dájúdájú Ọgbà Ìdẹ̀ra, òhun ni ibùgbé (rẹ̀).
79:42
Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa Àkókò náà pé: “Ìgbà wo l’ó máa ṣẹlẹ̀?”
79:43
Níbo ni ìwọ wà sí ìmọ̀ rẹ̀ ná?[1]
79:44
Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni òpin ìmọ̀ nípa rẹ̀ wà.
79:45
Ìwọ kúkú ni olùkìlọ̀ fún ẹni tó ń páyà rẹ̀.
79:46
Ní ọjọ́ tí wọ́n máa rí i, wọn máa dà bí ẹni pé wọn kò gbé ilé ayé tayọ ìrọ̀lẹ́ tàbí ìyálẹ̀ta (ọjọ́) kan.