80:1
Ó fajú ro, ó sì pẹ̀yìndà[1]
80:2
nítorí pé afọ́jú wá bá a.
80:3
Kí sì l’ó máa fi mọ̀ ọ́ pé ó ṣeé ṣe kí ó ṣàfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú àìgbàgbọ́)
80:4
tàbí kí ó gbọ́ ìrántí, kí ìrántí náà sì ṣe é ní àǹfààní?
80:5
Ní ti ẹni tí ó ka ara rẹ̀ kún ọlọ́rọ̀,
80:6
òun ni ìwọ tẹ́tí sí.
80:7
Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ bí kò bá ṣe àfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú àìgbàgbọ́).
80:8
Ní ti ẹni tí ó sì wá bá ọ, tó ń yára gágá (sí ìrántí, ìyẹn afọ́jú),
80:9
tí ó sì ń páyà (Allāhu),
80:10
ìwọ kò sì kọbi ara sí i.
80:11
Rárá (kò tọ́ bẹ́ẹ̀). Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ìrántí.
80:12
Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó rántí rẹ̀.
80:13
(Al-Ƙur’ān) wà nínú àwọn tàkádà alápọ̀n-ọ́nlé,
80:14
A gbé e ga, A sì ṣe é ní mímọ́
80:15
ní ọwọ́ àwọn òǹkọtíà (ìyẹn, àwọn mọlāika),
80:16
àwọn alápọ̀n-ọ́nlé, àwọn ẹni rere.
80:17
Wọ́n ti fi ènìyàn gégùn-ún (nípa) bí ó ṣe jẹ́ aláìmoore jùlọ!
80:18
Kí sì ni Allāhu fi ṣẹ̀dá rẹ̀?
80:19
Nínú àtọ̀ l’Ó ti ṣẹ̀dá rẹ̀. Ó sì pèbùbù (ẹ̀yà-ara) rẹ̀.
80:20
Lẹ́yìn náà, Ó ṣe ọ̀nà àtiwáyé ní ìrọ̀rùn fún un.
80:21
Lẹ́yìn náà, Ó máa pa á. Ó sì máa fi sínú sàréè.
80:22
Lẹ́yìn náà, nígbà tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa gbé e dìde.
80:23
Rárá o! Ènìyàn kò tí ì ṣe n̄ǹkan tí Allāhu pa láṣẹ fún un.
80:24
Nítorí náà, kí ènìyàn wòye sí oúnjẹ rẹ̀.
80:25
Dájúdájú Àwa ń rọ òjò ní púpọ̀.
80:26
Lẹ́yìn náà, A mú ilẹ̀ sán kànkàn.
80:27
A sì mú kóró èso hù jáde láti inú rẹ̀;
80:28
àti èso àjàrà àti kànnáfùrù,
80:29
àti igi òróró Zaetūn àti dàbínù,
80:30
àti àwọn ọgbà tó kún fún igi,
80:31
àti àwọn èso (mìíràn) pẹ̀lú ewé tí ẹranko ń jẹ, (A mú wọn hù jáde).
80:32
(Wọ́n jẹ́ n̄ǹkan) ìgbádùn fún ẹ̀yin àti àwọn ẹran-ọ̀sìn yín.
80:33
Nígbà tí fífọn sínú ìwo nígbà kejì bá ṣẹlẹ̀,
80:34
ní ọjọ́ tí ènìyàn yóò sá fún arákùnrin rẹ̀,
80:35
àti ìyá rẹ̀ àti bàbá rẹ̀,
80:36
àti ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀.
80:37
Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ní ọjọ́ yẹn l’ó ti ní ọ̀ràn tó máa tó o ó rán.
80:38
Àwọn ojú kan lọ́jọ́ yẹn yóò mọ́lẹ̀.
80:39
Wọn yó máa rẹ́rìn-ín, wọn yó sì máa dunnú.
80:40
Àwọn ojú kan lọ́jọ́ yẹn ni eruku yó sì bò mọ́lẹ̀.
80:41
Òkùnkùn yó sì bò wọ́n mọ́lẹ̀.
80:42
Àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni aláìgbàgbọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.