81:1
Nígbà tí wọ́n bá ká òòrùn kóróbójó dànù,
81:2
àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri,
81:3
àti nígbà tí wọ́n bá mú àwọn àpáta rìn (kúrò ní àyè wọn, tí wọ́n kù wọ́n dànù),
81:4
àti nígbà tí wọ́n bá pa àwọn ràkúnmí aboyún tì,
81:5
àti nígbà tí wọ́n bá ko àwọn ẹranko jọ,
81:6
àti nígbà tí wọ́n bá mú àwọn agbami odò gbiná,
81:7
àti nígbà tí wọ́n bá so àwọn ẹ̀mí pọ̀ mọ́ra wọn, (ẹni rere pẹ̀lú ẹni rere, ẹni ibi pẹ̀lú ẹni ibi)
81:8
àti nígbà tí ọmọbìnrin tí wọ́n bò mọ́lẹ̀ láàyè bá bèèrè pé
81:9
ẹ̀ṣẹ̀ wo ni wọ́n pa òun fún,
81:10
àti nígbà tí wọ́n bá ṣí àwọn tákàdá (iṣẹ́ ẹ̀dá) sílẹ̀,
81:11
àti nígbà tí wọ́n bá ká sánmọ̀ kúrò lókè,
81:12
àti nígbà tí wọ́n bá mú iná Jẹhīm jò fòfò,
81:13
àti nígbà tí wọ́n bá sún Ọgbà Ìdẹ̀ra mọ́ (àwọn onígbàgbọ́ òdodo),
81:14
(nígbà náà ni) ẹ̀mí (kọ̀ọ̀kan) yóò mọ ohun tí ó mú wá (nínú iṣẹ́ ire àti iṣẹ́ ibi).
81:15
Nítorí náà, Èmi (Allāhu) ń fi àwọn ìràwọ̀ tó ń yọ ní alẹ́, tó ń wọ̀ọ̀kùn ní ọ̀sán búra,
81:16
(ìyẹn) àwọn ìràwọ̀ tó ń rìn lọ rìn bọ̀, tó ń wọ̀ọ̀kùn sí ibùwọ̀ wọn.
81:17
Mo tún fi alẹ́ nígbà tí ó bá lọ búra.[1]
81:18
Mo tún fi òwúrọ̀ nígbà tí ó bá mọ́lẹ̀ búra.
81:19
Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán Jibrīl) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé,[1]
81:20
alágbára, ẹni pàtàkì ní ọ̀dọ̀ Ẹni t’Ó ni Ìtẹ́-ọlá,
81:21
ẹni tí wọ́n ń tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ níbẹ̀ yẹn (nínú sánmọ̀), olùfọkàntán.
81:22
Àti pé ẹni yín (Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) kì í ṣe wèrè.
81:23
Ó kúkú rí i nínú òfurufú kedere.[1]
81:24
Àti pé kì í ṣe ahun (tàbí ẹni-afurasí) lórí ìró ìkọ̀kọ̀ (tí A fi ránṣẹ́ sí i).
81:25
Al-Ƙur’ān kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) aṣ-Ṣaetọ̄n, ẹni ẹ̀kọ̀.
81:26
Nítorí náà, ibo l’ẹ̀ ń lọ?
81:27
Kí sì ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá.
81:28
(Ó wà) fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti dúró déédé.
81:29
Ẹ̀yin kò sì níí fẹ́ (láti dúró déédé) àyàfi tí Allāhu bá fẹ́, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.