al-Infitar (الإِنْفِطَار)

Yoruba:Mikail - Yoruba:Mikail

Chapter 82 • 19 verses • Meccan

← Previous Chapter Next Chapter →
82:1 Nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,[1]
82:2 àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri,
82:3 àti nígbà tí àwọn ibúdò bá ṣàn jára wọn,
82:4 àti (nígbà tí A bá ta ilẹ̀ sókè), tí A sì mú àwọn òkú jáde (láàyè) láti inú àwọn sàréè,
82:5 (nígbà náà ni) ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò mọ ohun tí ó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun tí ó fi sẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀).
82:6 Ìwọ ènìyàn, kí ni ó tàn ọ́ jẹ nípa Olúwa rẹ, Alápọ̀n-ọ́nlé,
82:7 Ẹni t’Ó ṣẹ̀dá rẹ? Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ ní pípé. Ó sì mú ọ dọ́gba jalẹ̀ léèyàn.
82:8 Ó to ẹ̀yà ara rẹ papọ̀ sínú èyíkéyìí àwòrán tí Ó fẹ́.
82:9 Rárá! Bí kò ṣe pé ẹ̀ ń pe Ọjọ́ ẹ̀san ní irọ́.
82:10 Dájúdájú àwọn ẹ̀ṣọ́ sì wà ní ọ̀dọ̀ yín.
82:11 (Wọ́n jẹ́) alápọ̀n-ọ́nlé, òǹkọ̀wé-iṣẹ́ ẹ̀dá.
82:12 Wọ́n mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
82:13 Dájúdájú àwọn ẹni rere yóò kúkú wà nínú ìgbádùn.
82:14 Dájúdájú àwọn ẹni ibi yó sì kúkú wà nínú iná Jẹhīm.
82:15 Wọn yóò wọ inú rẹ̀ ní Ọjọ́ ẹ̀san.
82:16 Wọn kò sì níí kúrò nínú rẹ̀.
82:17 Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san?
82:18 Lẹ́yìn náà, kí ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san?
82:19 (Ọjọ́ ẹ̀san ni) ọjọ́ tí ẹ̀mí kan kò níí kápá kiní kan fún ẹ̀mí kan. Gbogbo àṣẹ ọjọ́ yẹn sì ń jẹ́ ti Allāhu.