al-Mutaffifin (المُطَفِّفِين)

Yoruba:Mikail - Yoruba:Mikail

Chapter 83 • 36 verses • Meccan

← Previous Chapter Next Chapter →
83:1 Ègbé ni fún àwọn olùdín-òṣùwọ̀n-kù,
83:2 àwọn (òǹtajà) tó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá wọn n̄ǹkan lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn,[1] wọ́n á gbà á ní ẹ̀kún,
83:3 nígbà tí àwọn (òǹtajà náà) bá sì lo ìwọ̀n fún àwọn (òǹrajà) tàbí lo òṣùwọ̀n fún wọn, wọn yóò dín in kù.
83:4 Ṣé àwọn wọ̀nyẹn kò mọ̀ dájú pé dájúdájú A máa gbé wọn dìde
83:5 ní Ọjọ́ ńlá kan?
83:6 Ní ọjọ́ tí àwọn ènìyàn yóò dìde dúró fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
83:7 Ní ti òdodo dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni burúkú (tó ń dín òṣùwọ̀n kù) kúkú máa wà nínú Sijjīn.
83:8 Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Sijjīn!
83:9 Ìwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ aburú ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sínú ilẹ̀ keje ni Sijjīn).
83:10 Ní ọjọ́ yẹn, ègbé ni fún àwọn olùpe-òdodo- nírọ́,
83:11 àwọn tó ń pe Ọjọ́ ẹ̀san ní irọ́.
83:12 Kò sì sí ẹni tó ń pè é ní irọ́ àyàfi gbogbo alákọyọ, ẹlẹ́ṣẹ̀.
83:13 Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa fún un, ó máa wí pé: “Àwọn àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ (nìwọ̀nyí).”
83:14 Rárá (al-Ƙur’ān kì í ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́) bí kò ṣe pé ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ aburú l’ó jọba lórí ọkàn wọn.
83:15 Rárá (kò rí bí wọ́n ṣe rò ó sí sẹ́), dájúdájú wọn yóò wà nínú gàgá, wọn kò sì níí rí Olúwa wọn ní ọjọ́ yẹn.
83:16 Lẹ́yìn náà, dájúdájú wọn yóò wọ inú iná Jẹhīm.
83:17 Lẹ́yìn náà, wọ́n máa sọ (fún wọn) pe: “Èyí ni ohun tí ẹ̀ ń pè ní irọ́.”
83:18 Ní ti òdodo, dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni rere wà nínú ‘illiyyūn.
83:19 Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ ‘illiyyūn!
83:20 Ìwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ rere ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sí òkè sánmọ̀ ni ‘illiyyūn).
83:21 Àwọn (mọlāika) tí wọ́n súnmọ́ Allāhu ń jẹ́rìí sí i.
83:22 Dájúdájú àwọn ẹni rere máa wà nínú ìgbádùn.
83:23 Wọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn.
83:24 Ìwọ yóò dá ìtutù ojú ìgbádùn mọ̀ nínú ojú wọn.
83:25 Wọn yóò máa fún wọn mu nínú ọtí onídèérí.
83:26 Àlùmísìkí ni (òórùn) ìparí rẹ̀. Kí àwọn alápàáǹtètè ṣàpáǹtètè nínú ìyẹn.
83:27 Tẹsnīm ni wọ́n yóò máa pòpọ̀ (mọ́ ọtí náà).
83:28 (Tẹsnīm ni) omi ìṣẹ́lẹ̀rú kan, tí àwọn olùsúnmọ́ (Allāhu) yóò máa mu.
83:29 Dájúdájú àwọn tó dẹ́ṣẹ̀, wọ́n máa ń fi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo rẹ́rìn-ín.
83:30 Nígbà tí wọ́n bá gba ẹ̀gbẹ́ wọn kọjá, (àwọn olùdẹ́ṣẹ̀) yóò máa ṣẹ́jú síra wọn ní ti yẹ̀yẹ́.
83:31 Nígbà tí wọ́n bá sì padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wọn, wọ́n á padà tí wọn yóò máa ṣe fáàrí.
83:32 Àti pé nígbà tí wọ́n bá rí (àwọn onígbàgbọ́ òdodo) wọ́n á wí pé: “Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni olùṣìnà.”
83:33 Àwa kò sì rán wọn ní iṣẹ́ olùṣọ́ sí wọn.
83:34 Nítorí náà, ní òní àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo yóò fi àwọn aláìgbàgbọ́ rẹ́rìn-ín.
83:35 Wọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn.
83:36 Ṣebí wọ́n ti fi ohun tí àwọn aláìgbàgbọ́ ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n lẹ́san (báyìí)?