al-Inshiqaq (الإِنْشِقَاق)

Yoruba:Mikail - Yoruba:Mikail

Chapter 84 • 25 verses • Meccan

← Previous Chapter Next Chapter →
84:1 Nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ
84:2 - ó gbọ́, ó sì tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ̀ ni. Ó sì di dandan fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀[1] -
84:3 àti nígbà tí A bá fẹ ilẹ̀ lójú,
84:4 ó máa ju ohun tí ó wà nínú rẹ̀ síta, ó sì máa pa sófo
84:5 - ó gbọ́, ó sì tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ̀ ni. Ó sì di dandan fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ - (ní ọjọ́ yẹn ni ẹ̀dá máa rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀)
84:6 Ìwọ ènìyàn dájúdájú ìwọ ń ṣe iṣẹ́ kárakára ní iṣẹ́ àṣepàdé Olúwa rẹ. O sì máa mú un pàdé Rẹ̀.
84:7 Nítorí náà, ní ti ẹni tí wọ́n bá fún ní ìwé iṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀,
84:8 láìpẹ́ A máa ṣe ìṣírò-iṣẹ́ (rẹ̀) ní ìṣírò ìrọ̀rùn.
84:9 Ó sì máa padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra) lẹ́ni ìdùnnú.
84:10 Ní ti ẹni tí wọ́n bá sì fún ní ìwé iṣẹ́ rẹ̀ láti ẹ̀yìn rẹ̀,[1]
84:11 láìpẹ́ ó máa kígbe ìparun.
84:12 Ó sì máa wọ inú Iná tó ń jó.
84:13 Dájúdájú ó ti wà láààrin àwọn ènìyàn rẹ̀ lẹ́ni ìdùnnú (sí àìgbàgbọ́ nílé ayé).
84:14 Dájúdájú ó lérò pé òun kò níí padà (sí ọ̀dọ̀ Allāhu ni).
84:15 Bẹ́ẹ̀ ni, (ó máa padà). Dájúdájú Olúwa rẹ̀ jẹ́ Olùríran nípa rẹ̀.
84:16 Nítorí náà, Èmi (Allāhu) ń fi àwòǹpapa búra.
84:17 Mo tún ń fi òru àti ohun tí ó kó jọ sínú rẹ̀ búra.
84:18 Mo tún ń fi òṣùpá nígbà tí ó bá dégbá (tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kún) búra.
84:19 Dájúdájú ẹ̀yin yóò máa bọ́ sínú wàhálà kan láti inú wàhálà kan.
84:20 Kí l’ó ṣe wọ́n ná tí wọn kò fi gbàgbọ́ ní òdodo?
84:21 Nígbà tí wọ́n bá sì ké al-Ƙur’ān fún wọn, wọn kò níí forí kanlẹ̀.
84:22 Rárá, ńṣe ni àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ń pè é ní irọ́.
84:23 Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ (sínú ọkàn wọn).
84:24 Nítorí náà, fún wọn ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
84:25 Àyàfi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ẹ̀san tí kò níí pin[1] ń bẹ fún wọn.