al-Buruj (البُرُوج)

Yoruba:Mikail - Yoruba:Mikail

Chapter 85 • 22 verses • Meccan

← Previous Chapter Next Chapter →
85:1 (Allāhu) fi sánmọ̀ tí àwọn ibùsọ̀ (òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀) wà nínú rẹ̀ búra.
85:2 Ó tún fi ọjọ́ tí wọ́n ṣe ní àdéhùn (ìyẹn Ọjọ́ Àjíǹde) búra.
85:3 Ó tún fi olùjẹ́rìí àti ohun tó jẹ́rìí sí búra.
85:4 A ṣẹ́bi lé àwọn tó gbẹ́ kòtò (iná),
85:5 (ìyẹn) iná tí wọ́n ń fi igi kò (nínú kòtò).
85:6 (Rántí) nígbà tí wọ́n jókòó sí ìtòsí rẹ̀.
85:7 Wọ́n sì ń wo ohun tí wọ́n ń ṣe fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
85:8 Wọn kò rí àlèébù kan (wọn kò sì kórira kiní kan) lára wọn bí kò ṣe pé, wọ́n ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu, Alágbára, Ẹlẹ́yìn,
85:9 Ẹni tí Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ni Ẹlẹ́rìí lórí gbogbo n̄ǹkan.
85:10 Dájúdájú àwọn tó fi ìnira kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, lẹ́yìn náà tí wọn kò ronú pìwàdà, ìyà iná Jahanamọ ń bẹ fún wọn. Ìyà iná tó ń jó sì wà fún wọn.
85:11 Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tiwọn ni àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá.
85:12 Dájúdájú ìgbámú ti Olúwa rẹ mà le.
85:13 Dájúdájú Òun ni Ó pìlẹ̀ (ẹ̀dá), Ó sì máa dá (ẹ̀dá) padà (fún àjíǹde).
85:14 Òun ni Aláforíjìn, Olólùfẹ́ (ẹ̀dá),
85:15 Òun l’Ó ni Ìtẹ́-ọlá, Ológo (Ẹni-ọ̀wọ̀ jùlọ),
85:16 Olùṣe-ohun-t’Ó-bá-fẹ́.
85:17 Ṣebí ìró àwọn ọmọ ogun ti dé ọ̀dọ̀ rẹ,
85:18 (ọmọ ogun) Fir‘aon àti (ìjọ) Thamūd?
85:19 Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ sì ń pe òdodo ní irọ́.
85:20 Allāhu sì yí wọn ká lẹ́yìn wọn.
85:21 Àmọ́ sá, ohun (tí A fi ránṣẹ́ sí ọ ni) al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé,
85:22 tí ó wà nínú wàláà tí wọ́n ń ṣọ́.