86:1
(Allāhu) fi sánmọ̀ àti Tọ̄riƙ búra.
86:2
Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Tọ̄riƙ?
86:3
Ìràwọ̀ tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ń tàn ròrò (ní alẹ́ ni).
86:4
Kò sí ẹ̀mí kan àfi kí ẹ̀ṣọ́ kan wà fún un (nínú àwọn mọlāika).
86:5
Nítorí náà, kí ènìyàn wòye sí ohun tí A fi ṣẹ̀dá rẹ̀.
86:6
Wọ́n ṣẹ̀dá rẹ̀ láti inú omi tó ń tú jáde kọ̀ọ́kọ̀ọ́.
86:7
Ó ń jáde láti ààrin ìbàdí ọkùnrin àti àwọn ẹfọ́nhà igbá-àyà obìnrin.
86:8
Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lóri ìdápadà rẹ̀
86:9
ní ọjọ́ tí wọ́n máa ṣe àyẹ̀wò àwọn (iṣẹ́) àṣepamọ́.
86:10
Nígbà náà, kò níí sí agbára tàbí alárànṣe kan fún un.
86:11
Allāhu fi sánmọ̀ tó ń rọ òjò ní ọdọọdún búra.
86:12
Ó tún fi ilẹ̀ tó ń sán kànkàn (fún híhùjáde èso) búra.
86:13
Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ọ̀rọ̀-ìpínyà (láààrin òdodo àti irọ́).
86:14
Kì í sì ṣe àwàdà.
86:15
Dájúdájú wọ́n ń déte gan-an.
86:16
Èmi náà sì ń déte gan-an.[1]
86:17
Nítorí náà, lọ́ra fún àwọn aláìgbàgbọ́. Lọ́ wọn lára sẹ́ fún ìgbà díẹ̀.