87:1
Ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni gíga jùlọ.
87:2
Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá. Ó sì ṣe (oríkèé-ríkèé rẹ̀) ní dọ́gbadọ́gba.
87:3
Ẹni tí Ó yan kádàrá (fún ẹ̀dá). Ó sì tọ́ ọ sọ́nà.[1]
87:4
Ẹni tí Ó mú koríko tútù hù jáde,
87:5
Ó sì sọ ọ́ di gbígbẹ tó dúdú.
87:6
Àwa yóò máa ké (al-Ƙur’ān) fún ọ. Ìwọ kò sì níí gbàgbé.
87:7
Àyàfi ohun tí Allāhu bá fẹ́.[1] Dájúdájú Ó mọ gban̄gba àti ohun tó pamọ́.
87:8
Àwa yó sì ṣe iṣẹ́ rere ní ìrọ̀rùn fún ọ.
87:9
Nítorí náà, ṣèrántí ní àyè tí ìrántí ti wúlò.[1]
87:10
Ẹni tí ó máa páyà (Allāhu) máa lo ìrántí.
87:11
Olórí-burúkú sì máa takété sí i.
87:12
(Òun sì ni) ẹni tí ó máa wọ inú Iná tó tóbi.
87:13
Lẹ́yìn náà, kò níí kú sínú rẹ̀, kò sì níí ṣẹ̀mí (àlàáfíà).
87:14
Dájúdájú ẹni tí ó bá ṣe àfọ̀mọ́ (ẹ̀sìn rẹ̀) ti jèrè.[1]
87:15
Ó sì rántí orúkọ Olúwa rẹ̀, ó sì kírun.
87:16
Rárá, ńṣe l’ẹ̀ ń gbé àjùlọ fún ìṣẹ̀mí ayé.
87:17
Ọ̀run sì lóore jùlọ, ó sì máa wà títí láéláé.
87:18
Dájúdájú èyí wà nínú àwọn tákàǹdá àkọ́kọ́,
87:19
tákàdá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti (Ànábì) Mūsā.