al-Ghashiyah (الغَاشِيَة)

Yoruba:Mikail - Yoruba:Mikail

Chapter 88 • 26 verses • Meccan

← Previous Chapter Next Chapter →
88:1 Ṣebí ọ̀rọ̀ nípa ohun tó máa bo ẹ̀dá mọ́lẹ̀ ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?
88:2 Àwọn ojú kan yóò wálẹ̀ (ní ti ìyẹpẹrẹ) ní ọjọ́ yẹn.
88:3 Wọ́n ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó (ni nílé ayé).
88:4 Wọ́n sì máa wọ inú Iná tó gbóná janjan (ní ọ̀run).
88:5 Wọ́n sì máa fún (wọn) ní omi ìṣẹ́lẹ̀rú gbígbóná mu.
88:6 Kò sí oúnjẹ kan fún wọn àyàfi igi ẹlẹ́gùn-ún gbígbẹ.
88:7 Kò níí mú wọn sanra. Kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ebi.
88:8 Àwọn ojú kan yó sì kún fún ìgbádùn ní ọjọ́ yẹn
88:9 nítorí pé (ó) yọ́nú sí (ẹ̀san) iṣẹ́ rẹ̀.
88:10 (Ó máa) wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra gíga.
88:11 Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ nínú rẹ̀.
88:12 Omi ìṣẹ́lẹ̀rú tó ń ṣàn wà nínú rẹ̀.
88:13 Àwọn ibùsùn tí wọ́n gbé sókè wà nínú rẹ̀,
88:14 àti àwọn ife ìmumi tí wọ́n gbé kalẹ̀ (sí àrọ́wọ́tó wọn),
88:15 àti àwọn ìrọ̀rí tí wọ́n tò sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn,
88:16 àti àwọn ìtẹ́ àtẹ́ẹ̀ká.
88:17 Nítorí náà, ṣé wọn kò wòye sí ràkúnmí, bí A ti ṣẹ̀dá rẹ̀ ni;
88:18 àti sánmọ̀, bí A ti ṣe gbé e sókè;
88:19 àti àpáta, bí A ti ṣe gbé e nàró (sínú ilẹ̀);
88:20 àti ilẹ̀, bí A ti ṣe tẹ́ ẹ sílẹ̀ pẹrẹsẹ?
88:21 Nítorí náà, ṣèrántí. Ìwọ kúkú ni olùṣèràntí.
88:22 Ìwọ kì í ṣe ajẹni-nípá lórí wọn
88:23 àfi ẹni tí ó bá pẹ̀yìndà (sí òdodo), tí ó sì ṣàì gbàgbọ́.
88:24 Allāhu sì máa jẹ ẹ́ níyà tó tóbi jùlọ.
88:25 Dájúdájú ọ̀dọ̀ Wa ni àbọ̀ wọn wà.
88:26 Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa l’A máa ṣe ìṣírò-iṣẹ́ wọn.