89:1
Allāhu fi àfẹ̀mọ́júmọ́ búra.
89:2
Ó tún fi àwọn òru mẹ́wàá kan búra.
89:3
Ó tún fi n̄ǹkan tí eéjì ń pín geerege àti n̄ǹkan tí eéjì kò pín geerege búra.
89:4
Ó tún fi òru nígbà tí ó bá dé búra.
89:5
Ǹjẹ́ ìbúra wà nínú ìyẹn fún onílàákàyè?
89:6
Ṣé o kò wòye sí bí Olúwa rẹ ti ṣe ọ̀rọ̀ ará ‘Ād,
89:7
(ìyẹn àwọn ìran) ’Irọm, àwọn òmìrán,
89:8
àwọn tí A kò dá irú wọn mọ́ sínú ìlú?
89:9
Àti àwọn Thamūd tí wọ́n gbẹ́ (ilé ìgbé) sínú àpáta nínú àfonúfojì,
89:10
àti Fir‘aon eléèkàn (ìyà)?
89:11
(Àwọn wọ̀nyí ni) àwọn tó tayọ ẹnu-ààlà nínú ìlú.
89:12
Wọ́n sì ṣe ìbàjẹ́ púpọ̀ sínú rẹ̀.
89:13
Olúwa rẹ sì rọ̀jò ìyà lé wọn lórí.
89:14
Dájúdájú Olúwa rẹ wà ní ibùṣọ́ (iṣẹ́ ẹ̀dá).
89:15
Nítorí náà, ní ti ènìyàn, nígbà tí Olúwa rẹ̀ bá dán an wò, tí Ó pọ́n ọn lé, tí Ó sì ṣe ìdẹ̀ra fún un, nígbà náà ó máa wí pé: “Olúwa mi ti pọ́n mi lé.”
89:16
Ṣùgbọ́n nígbà tí Ó bá dán an wò, tí Ó gán arísìkí rẹ̀ lé e lọ́wọ́, nígbà náà ó máa wí pé: “Olúwa mi ti yẹpẹrẹ mi.”
89:17
Rárá, kò rí bẹ́ẹ̀, bí kò ṣe pé, ẹ̀yin kò ṣàpọ́nlé ọmọ-òrukàn.
89:18
Àti pé ẹ̀yin kò gbẹra yín lóǹgbẹ láti fún mẹ̀kúnnù ní oúnjẹ.
89:19
Ẹ tún ń jẹ ogún ní ìjẹkújẹ.
89:20
Àti pé ẹ nífẹ̀ẹ́ sí dúkìá ní ìfẹ́ púpọ̀.
89:21
Rárá, (kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀). Nígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní mímì tìtì (tó rún wómúwómú, tí kò sí kòtò, tí kò sí gelemọ),
89:22
(tí) Olúwa rẹ dé pẹ̀lú àwọn mọlāika ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ọ̀wọ̀ọ̀wọ́,
89:23
ní ọjọ́ yẹn ni wọ́n máa mú iná Jahanamọ wá. Ní ọjọ́ yẹn, ènìyàn yóò rántí (ọ̀rọ̀ ara rẹ̀). Báwo sì ni ìrántí náà ṣe lè wúlò fún un!
89:24
Ó máa wí pé: “Yéè, èmi ìbá ti ti (iṣẹ́ rere) síwájú fún ìṣẹ̀mí mi.”
89:25
Ní ọjọ́ yẹn, ẹnì kan kò lè fi ìyà jẹ (ẹ̀dá) bí irú ìyà (tí) Allāhu (yóò fi jẹ ẹ́).
89:26
Ẹnì kan kò sì lè de (ẹ̀dá) ní ìgbèkùn bí irú ìgbèkùn (tí) Allāhu (yóò fi dè é).
89:27
Ìwọ ẹ̀mí olùfọ̀kànbalẹ̀,
89:28
padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ní olùyọ́nú, ẹni ìyọ́nú.
89:29
Nítorí náà, wọlé sáààrin àwọn ẹrúsìn Mi.
89:30
Wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra Mi.