90:1
Èmi (Allāhu) ń fi ìlú yìí[1] búra.
90:2
Ìwọ sì ní ẹ̀tọ́ sí ìlú yìí (láti jagun nínú rẹ̀).[1]
90:3
Èmi (Allāhu) ń fi òbí àti ohun tó bí búra.
90:4
Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn sínú ìṣòro.
90:5
Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò ní agbára lórí òun ni?
90:6
Ó (sì) ń wí pé: “Èmi ti bàná dúkìá ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ (láti fi tako Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -)”
90:7
Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò rí òun ni?
90:8
Ṣé A kò ṣe ojú méjì fún un?
90:9
Àti ahọ́n pẹ̀lú ètè méjì (tí A ṣe fún un)?
90:10
A sì fi ọ̀nà méjì mọ̀ ọ́n.
90:11
Kò sì lọ rin ojú-ọ̀nà orí àpáta tó ṣòroó gùn fún ìgbàlà ẹ̀mí níbi Iná!
90:12
Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ ojú-ọ̀nà orí àpáta tó ṣòroó gùn fún ìgbàlà ẹ̀mí?
90:13
(Òhun ni) títú ẹrú sílẹ̀ lóko ẹrú.
90:14
Tàbí fífún ènìyàn ní oúnjẹ ní ọjọ́ ebi.
90:15
(Ẹ lè fún) ọmọ-òrukàn nínú ẹbí,
90:16
tàbí mẹ̀kúnnù tí kò ní gá tí kò ní go (olòṣì paraku).
90:17
Lẹ́yìn náà, kí ó wà nínú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ń gbara wọn níyànjú sùúrù ṣíṣe, tí wọ́n sì tún ń gbara wọn níyànjú àánú ṣíṣe.
90:18
Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò ọwọ́ ọ̀tún.
90:19
Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, àwọn ni èrò ọwọ́ òsì.[1]
90:20
Wọ́n máa ti àwọn ìlẹ̀kùn Iná pa mọ́ wọn lórí pátápátá.