adh-Dhariyat (الذَّارِيَات)

Yoruba:Mikail - Yoruba:Mikail

Chapter 51 • 60 verses • Meccan

← Previous Chapter Next Chapter →
51:1 Allāhu fi atẹ́gùn tó ń tu erùpẹ̀ jáde nílẹ̀ ní títu-jáde tààrà búra.
51:2 Allāhu fi àwọn ẹ̀ṣújò tó ru òjò tó wúwo búra.
51:3 Allāhu fi àwọn ọkọ̀ ojú-omi tó ń rìn pẹ̀lú ìrọ̀rùn búra.
51:4 Allāhu fi àwọn mọlāika tó ń pín n̄ǹkan tí Ó ti pín fún ẹ̀dá búra.
51:5 Òdodo mà ni ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún yín.
51:6 Àti pé dájúdájú ẹ̀san iṣẹ́ máa ṣẹlẹ̀.
51:7 Allāhu tún fi sánmọ̀ ọlọ́ṣọ̀ọ́ tó gún régé búra.
51:8 Dájúdájú ẹ̀yin wà lórí ọ̀rọ̀ tó ń takora wọn (nípa al-Ƙur’ān).
51:9 Ẹni tí wọ́n ń ṣẹ́ lórí kúrò níbi al-Ƙur’ān ni ẹni tí Wọ́n ti ṣẹ́ lórí kúrò níbẹ̀ (láti inú Laohul-Mahfūṭḥ).
51:10 Ègbé ni fún àwọn òpùrọ́;
51:11 àwọn tí wọ́n wà nínú àìmọ̀kan tó gbópọn tí wọ́n ti gbàgbéra.
51:12 tí wọ́n ń bèèrè ìgbà tí Ọjọ́ Ẹ̀san máa ṣẹlẹ̀.
51:13 Ní ọjọ́ náà sì ni wọn yóò máa fi Iná jẹ wọ́n níyà.
51:14 Ẹ tọ́ ìyà yín wò. Èyí ni n̄ǹkan tí ẹ ti ń wá pẹ̀lú ìkánjú.
51:15 Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) yóò wà nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra pẹ̀lú àwọn omi odò ìṣẹ́lẹ̀rú (ní ìsàlẹ̀ rẹ̀).
51:16 Wọn yóò máa gba n̄ǹkan tí Olúwa wọn bá fún wọn. Dájúdájú wọ́n ti jẹ́ olùṣe-rere ṣíwájú ìyẹn.
51:17 Wọ́n máa ń sun oorun díẹ̀ nínú òru.
51:18 Wọ́n máa ń tọrọ àforíjìn ní àfẹ̀mọ́júmọ́.
51:19 Nínú dúkìá wọn, wọ́n ní ojúṣe tí wọ́n ń ṣe fún alágbe àti ẹni tí A ṣe arísìkí ní èèwọ̀ fún.
51:20 Àwọn àmì wà ní orí ilẹ̀ fún àwọn alámọ̀dájú.
51:21 Nínú ẹ̀mí ara yín gan-an (àmì ìyanu wà nínú rẹ̀). Ṣé ẹ kò ríran ni?
51:22 Arísìkí yín àti ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún yín wà nínú sánmọ̀.
51:23 Nítorí náà, Mó fi Olúwa sánmọ̀ àti ilẹ̀ búra, dájúdájú òdodo ni (ọ̀rọ̀ náà) gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ òdodo pé ẹ̀ ń fẹnu sọ̀rọ̀.
51:24 Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ àwọn àlejò (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, àwọn alápọ̀n-ọ́nlé, ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?
51:25 (Rántí) nígbà tí wọ́n wọlé tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì sọ pé: “Àlàáfíà (fún ọ).” Òun náà sọ pé: “Àlàáfíà (fún yín), ẹ̀yin àjòjì ènìyàn.”
51:26 Ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará ilé rẹ̀, ó sì dé pẹ̀lú ọmọ màálù tó ní ọ̀rá (tí wọ́n ti yangbẹ).
51:27 Ó gbé e súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn. Ó sì sọ pé: “Ṣé ẹ kò níí jẹun ni?”
51:28 Nígbà náà, ìbẹ̀rù wọn sì mú un.[1]. Wọ́n sọ pé: “Má ṣe páyà.” Wọ́n sì fún un ní ìró ìdùnnú nípa bíbí ọmọkùnrin kan tí ó máa ní ìmọ̀.
51:29 Nígbà náà, ìyàwó rẹ̀ wọlé pẹ̀lú igbe, ó sì gbára rẹ̀ lójú, ó sọ pé: “Arúgbó, àgàn (mà ni mí)!”
51:30 Wọ́n sọ pé: “Báyẹn ni Olúwa rẹ sọ. Dájúdájú Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.”
51:31 (Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “Kí tún ni ọ̀rọ̀ tí ẹ bá wá, ẹ̀yin Òjíṣẹ́?”
51:32 Wọ́n sọ pé: “Dájúdájú Wọ́n rán wa níṣẹ́ sí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ni
51:33 nítorí kí á lè fi òkúta amọ̀ (sísun) ránṣẹ́ sí wọn.
51:34 Wọ́n ti fi àmì sí i lára lọ́dọ̀ Olúwa rẹ fún àwọn alákọyọ.”
51:35 Nítorí náà, A mú àwọn tó jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo jáde kúrò nínú (ìlú náà).
51:36 A kò sì rí nínú (ìlú náà) yàtọ̀ sí ilé kan tó jẹ́ ti àwọn mùsùlùmí.
51:37 A sì fi àmì kan sílẹ̀ nínú (ìlú náà) fún àwọn tó ń páyà ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
51:38 (Àmì tún wà) lára (Ànábì) Mūsā. Nígbà tí A fi ẹ̀rí pọ́nńbélé rán an níṣẹ́ sí Fir‘aon.
51:39 Ṣùgbọ́n ó lo gbogbo agbára rẹ̀ láti kẹ̀yìn sí òdodo. Ó sì wí pé: “Òpìdán tàbí wèrè kan (nìyí).”
51:40 Nítorí náà, A mú òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀. A sì jù wọ́n sínú agbami odò nígbà tí ó jẹ́ alábùkù.
51:41 (Àmì tún wà) lára ìjọ ‘Ād. (Rántí) nígbà tí A rán atẹ́gùn ìparun sí wọn.
51:42 Kò fi kiní kan tó fẹ́ sí lára sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ àfi kí ó sọ ọ́ di n̄ǹkan tó kẹfun.[1]
51:43 (Àmì tún wà) lára ìjọ Thamūd. (Rántí) nígbà tí A sọ fún wọn pé: “Ẹ jayé fún ìgbà díẹ̀ ná.”
51:44 Wọ́n ṣègbéraga sí àṣẹ Olúwa wọn. Nítorí náà, iná láti ojú sánmọ̀ gbá wọn mú; wọ́n sì ń wò bọ̀ọ̀.
51:45 Wọn kò lè dìde nàró. Wọn kò sì lè ran ara wọn lọ́wọ́.
51:46 Àti ìjọ Nūh tí ó ṣíwájú (wọn), dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ arúfin.
51:47 Àti pé sánmọ̀, A mọ ọ́n (sí òkè yín) pẹ̀lú agbára. Dájúdájú Àwa sì ni Alágbára (tí a mú un tóbi).
51:48 Àti ilẹ̀, A ṣe é ní ìtẹ́. (Àwa sì ni) olùtẹ́-ilẹ̀ sílẹ̀ tó dára.
51:49 Àti pé gbogbo n̄ǹkan ni A ṣẹ̀dá rẹ̀ ní oríṣi méjì-méjì nítorí kí ẹ lè lo ìrántí.[1]
51:50 Nítorí náà, ẹ sá lọ sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípa ìronúpìwàdà). Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fún yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
51:51 Ẹ má ṣe mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fún yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
51:52 Báyẹn ni (ọ̀rọ̀ ṣe rí)! Òjíṣẹ́ kan kò wá bá àwọn tó ṣíwájú wọn àfi kí wọ́n wí pé: “Òpìdán tàbí wèrè ni.”
51:53 Ṣé wọn sọ àsọọ́lẹ̀ nípa rẹ̀ láààrin ara wọn ni? Rárá o! Ìjọ olùtayọ-ẹnu-ààlà ni wọ́n ni.
51:54 Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn ná. Ìwọ kì í ṣe ẹni tí A máa bá wí.
51:55 Ṣèrántí nítorí pé, dájúdájú ìrántí máa wúlò fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
51:56 Àti pé Èmi kò ṣẹ̀dá àlùjànnú àti ènìyàn bí kò ṣe pé kí wọ́n lè jọ́sìn fún Mi.
51:57 Èmi kò gbèrò arísìkí kan láti ọ̀dọ̀ wọn. Èmi kò sì gbèrò pé kí wọ́n máa bọ́ Mi.
51:58 Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùpèsè, Alágbára líle.
51:59 Dájúdájú ìpín ìyà tí ó máa jẹ àwọn tó ṣàbòsí (wọ̀nyí) ni irú ìpín ìyà tí ó jẹ ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ (irú) wọn. Nítorí náà, kí wọ́n má ṣe kán Mi lójú (nípa ìyà wọn).
51:60 Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ní ọjọ́ wọn tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.