50:1
Ƙọ̄f. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1] (Allāhu fi) al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé búra.
50:2
Ṣùgbọ́n wọ́n ṣèèmọ̀ nítorí pé olùkìlọ̀ kan wá bá wọn láti ààrin ara wọn. Àwọn aláìgbàgbọ́ sì wí pé: “Èyí ni ohun ìyanu.”
50:3
Ṣé nígbà tí a bá ti kú, tí a ti di erùpẹ̀ (ni a óò tún jí dìde padà). Ìyẹn ni ìdápadà tó jìnnà (sí n̄ǹkan tí ó lè ṣẹlẹ̀).
50:4
Dájúdájú A ti mọ ohun tí ilẹ̀ ń mú jẹ nínú wọn. Tírà (iṣẹ́ ẹ̀dá) tí wọ́n ń ṣọ́ sì wà ní ọ̀dọ̀ Wa.
50:5
Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n pe òdodo (al-Ƙur’ān) ní irọ́ nígbà tí ó dé bá wọn. Nítorí náà, wọ́n ti wà nínú ìdààmú.
50:6
Ṣé wọn kò wo sánmọ̀ òkè wọn bí A ti ṣe mọ ọ́n pa àti (bí) A ti ṣe ṣe é ní ọ̀ṣọ́, tí kò sì sí àlàfo sísán kan lára rẹ̀?
50:7
Àti pé ilẹ̀, A tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ. A sì ju àwọn àpáta tó dúró gbagidi sínú rẹ̀. A sì mú oríṣiríṣi irúgbìn tó dára hù jáde láti inú rẹ̀.
50:8
(Ó jẹ́) àríwòye àti ìrántí fún gbogbo ẹrúsìn tó ń ṣẹ́rí padà (síbi òdodo).
50:9
A ń sọ omi ìbùkún kalẹ̀ láti sánmọ̀. A sì ń fi mú àwọn ọgbà oko àti àwọn èso tí wọ́n ń kórè rẹ̀ hù jáde.
50:10
(A tún mú) igi dàbínù hù ga, tí àwọn èso orí rẹ̀ so jìgbìnnì.
50:11
Arísìkí ni fún àwọn ẹrú (Allāhu). A sì ń fi sọ òkú ilẹ̀ di àyè. Báyẹn ni ìjáde ẹ̀dá (láti inú sàréè yó ṣe rí).
50:12
Àwọn ènìyàn (Ànábì) Nūh, àwọn ènìyàn Rass àti àwọn (ènìyàn) Thamūd pe òdodo ní irọ́ ṣíwájú wọn.
50:13
Àti àwọn ‘Ād, Fir‘aon àti àwọn ọmọ ìyá (Ànábì) Lūt,
50:14
àti àwọn ará ’Aekah àti àwọn ìjọ Tubba‘u; gbogbo wọn pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́. Nítorí náà, ìlérí Mi sì kò (lórí wọn).
50:15
Ǹjẹ́ ìṣẹ̀dá àkọ́kọ́ kó agara bá Wa bí? Rárá, wọ́n wà nínú iyèméjì (àti ìrújú) nípa ìṣẹ̀dá (wọn) ní ọ̀tun ni.
50:16
Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn. A sì mọ ohun tí ẹ̀mí rẹ̀ ń sọ fún un ní ròyíròyí. Àwa sì súnmọ́ ọn ju isan ọrùn rẹ̀.[1]
50:17
(Rántí) nígbà tí (mọlāika) àwọn olùgbọ̀rọ̀-sílẹ̀ méjì bá bẹ̀rẹ̀sí gba ọ̀rọ̀ (sílẹ̀), tí ọ̀kan jókòó sí ọ̀tún, tí ọ̀kan jókòó sí òsì.
50:18
(Ẹnì kan) kò sì níí sọ ọ̀rọ̀ kan àyàfi kí ẹ̀ṣọ́ kan ti wà níkàlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ (fún àkọsílẹ̀ rẹ̀).
50:19
Àti pé ìpọ́kàkà ikú yóò dé láti fi òdodo ọ̀run rinlẹ̀. Ìyẹn ni ohun tí ìwọ ń sá fún.
50:20
Wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. Ìyẹn ni ọjọ́ ìlérí náà.
50:21
Ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò wá pẹ̀lú olùdarí kan àti ẹlẹ́rìí kan (nínú àwọn mọlāika).
50:22
Dájúdájú ìwọ ti wà nínú ìgbàgbéra níbi èyí. A sì ti ṣí èbìbò (ojú) rẹ kúrò fún ọ báyìí. Nítorí náà, ìríran rẹ yóò ríran kedere ní òní.
50:23
(Mọlāika) alábàárìn rẹ̀ yóò sọ pé: “Èyí ti wà nílẹ̀ ni ohun tí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ mi (gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀).”
50:24
Ẹ̀yin mọlāika méjèèjì,[1] ẹ ju gbogbo aláìgbàgbọ́ olóríkunkun sínú iná Jahanamọ.
50:25
(Ẹ ju) ẹni tí ó dènà iṣẹ́ rere, alákọyọ, oníyèméjì (sínú Iná).
50:26
Ẹni tó mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu, ẹ jù ú sínú ìyà líle.
50:27
(aṣ-Ṣaetọ̄n) alábàárìn rẹ̀ yóò wí pé: “Olúwa wa, èmi kọ́ ni mo mú un tayọ ẹnu-ààlà, ṣùgbọ́n ó ti wà nínú ìṣìnà tó jìnnà (sí òdodo) tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.”
50:28
(Allāhu) yóò sọ pé: “Ẹ má se ṣàríyànjiyàn lọ́dọ̀ Mi. Mo kúkú ti ṣe ìlérí fún yín ṣíwájú.
50:29
Wọn kò sì lè yí ọ̀rọ̀ náà padà ní ọ̀dọ̀ Mi. Èmi kò sì níí ṣe àbòsí sí àwọn ẹrú Mi.”
50:30
(Rántí) ọjọ́ tí A óò sọ fún iná Jahanamọ pé: Ṣèbí o ti kún?” Ó sì máa sọ pé: “Ṣèbí àfikún tún wà?”
50:31
Wọ́n máa sún Ọgbà Ìdẹ̀ra mọ́ àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu). Kò sì níí jìnnà (sí wọn).
50:32
Èyí ni ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún gbogbo olùronúpìwàdà, olùṣọ́ (òfin Allāhu).
50:33
Ẹnikẹ́ni tí ó bá páyà Allāhu ní ìkọ̀kọ̀, tí ó tún dé pẹ̀lú ọkàn tó ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípa ìronúpìwàdà),
50:34
(A óò sọ fún wọn pé): “Ẹ wọ inú (Ọgbà Ìdẹ̀ra) pẹ̀lú àlàáfíà. Ìyẹn ni ọjọ́ gbére.”
50:35
Ohun tí wọ́n ń fẹ́ wà nínú rẹ̀. Àlékún sì tún wà ní ọ̀dọ̀ Wa.
50:36
Mélòó mélòó nínú àwọn ìjọ tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn. Wọ́n sì ní agbára jù wọ́n lọ. (Nígbà tí ìyà dé) wọ́n sá àsálà kiri nínú ìlú. Ǹjẹ́ ibùsásí kan wà (fún wọn bí?)
50:37
Dájúdájú ìrántí wà nínú ìyẹn fún ẹni tó ní ọkàn tàbí ẹni tó fi etí sílẹ̀, tó wà níbẹ̀ (pẹ̀lú ọkàn rẹ̀).
50:38
Dájúdájú A ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan tó wà láààrin àwọn méjèèjì fún ọjọ́ mẹ́fà. Kò sì rẹ̀ Wá rárá (áḿbọ̀sìbọ́sí pé A óò sinmi ní ọjọ́ keje).
50:39
Nítorí náà, ṣe sùúrù lórí ohun tí wọ́n ń wí. Kí o sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Olúwa Rẹ[1] ṣíwájú yíyọ òòrùn àti wíwọ̀ (rẹ̀).
50:40
Àti pé ní òru àti ni ẹ̀yìn ìrun ṣe àfọ̀mọ́ fún Un.
50:41
Kí o sì tẹ́tí sí (ọ̀rọ̀) ọjọ́ tí olùpèpè yóò pèpè láti àyè kan tó súnmọ́.
50:42
Ọjọ́ tí wọn yóò gbọ́ igbe pẹ̀lú òdodo. Ìyẹn ni ọjọ́ ìjáde ẹ̀dá (láti inú sàréè).
50:43
Dájúdájú Àwa, Àwa l’À ń sọ ẹ̀dá di alààyè. A sì ń sọ ọ́ di òkú. Ọ̀dọ̀ Wa sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.
50:44
(Rántí) ọjọ́ tí ilẹ̀ yóò fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ mọ́ wọn lára, (tí wọn yóò máa) yára (jáde láti inú ilẹ̀). Ìyẹn ni àkójọ tó rọrùn fún Wa.
50:45
Àwa nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń wí. Ìwọ kò sì níí jẹ wọ́n nípá (láti gbàgbọ́). Nítorí náà, fi al-Ƙur’ān ṣe ìrántí fún ẹni tí ó ń páyà ìlérí Mi.