al-Qiyamah (القِيَامَة)

Yoruba:Mikail - Yoruba:Mikail

Chapter 75 • 40 verses • Meccan

← Previous Chapter Next Chapter →
75:1 Èmi (Allāhu) ń fi Ọjọ́ Àjíǹde búra.
75:2 Mo tún ń fi ẹ̀mí tó máa dá ara rẹ̀ ní ẹ̀bi búra.
75:3 Ṣé ènìyàn lérò pé A kò níí kó àwọn eegun rẹ̀ jọ ni?
75:4 Rárá. (À ń jẹ́) Alágbára láti to eegun ọmọníka rẹ̀ dọ́gba.
75:5 Rárá ènìyàn fẹ́ máa ṣe aburú lọ bẹ́ẹ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé rẹ̀
75:6 ni ó fi ń bèèrè pé: “Ìgbà wo ni Ọjọ́ Àjíǹde?”
75:7 Nígbà tí ojú bá rí ìdààmú tó sì yà sílẹ̀ tí kò lè padé,
75:8 àti (nígbà) tí òṣùpá bá wọ̀ọ̀kùn,
75:9 àti (nígbà) tí wọ́n bá pa òòrùn àti òṣùpá pọ̀ mọ́ra wọn tí ìmọ́lẹ̀ méjèèjì pòóró,
75:10 ènìyàn yóò wí ní ọjọ́ yẹn pé: “Níbo ni ibùsásí wà?”
75:11 Rárá, kò sí ibùsásí.
75:12 Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni ibùdúró ní ọjọ́ yẹn.
75:13 Wọ́n máa fún ènìyàn ní ìró ní ọjọ́ yẹn nípa ohun tó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun tó fi kẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀).
75:14 Ṣebí ènìyàn dá ara rẹ̀ mọ̀,
75:15 ìbáà mú àwọn àwáwí rẹ̀ wá.
75:16 Má ṣe gbé ahọ́n rẹ sí ìmísí láti kánjú ké e.
75:17 Dájúdájú Àwa l’A máa ṣe àkójọ rẹ̀ (sínú ọkàn rẹ) àti kíké rẹ̀.
75:18 Nígbà tí A bá ń ké e (fún ọ), kí o sì máa tẹ̀lé kíké rẹ̀.
75:19 Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa l’A máa ṣe àlàyé rẹ̀ fún ọ.
75:20 Kò rí bẹ́ẹ̀, bí kò ṣe pé, ẹ nífẹ̀ẹ́ ayé ni.
75:21 Ẹ sì ń gbé ọ̀run jù sílẹ̀.
75:22 Àwọn ojú kan ní ọjọ́ yẹn yóò tutù (fún ìdùnnú).
75:23 Olúwa wọn ni wọn yóò máa wò.
75:24 Àwọn ojú kan ní ọjọ́ yẹn sì máa bàjẹ́.
75:25 (Ojú náà) yóò mọ̀ dájú pé wọ́n máa fi aburú kan òhun.
75:26 Kò rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí ẹ̀mí bá dé gògòńgò.
75:27 A sì máa sọ pé: “Ǹjẹ́ olùpọfọ̀ kan wà bí (tí ó máa pọfọ̀ láti gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú)?
75:28 Ó sì máa dá a lójú pé dájúdájú ìpínyà ayé ti dé.
75:29 Ojúgun yó sì lọ́mọ́ ojúgun.
75:30 Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì ni wíwa ẹ̀dá lọ ní ọjọ́ yẹn.
75:31 Kò kúkú gba òdodo gbọ́, kò sì kírun.
75:32 Ṣùgbọ́n ó pe òdodo ní irọ́. Ó sì kẹ̀yìn sí i.
75:33 Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ń ṣe fáàrí.
75:34 (Ìparun nílé ayé) ló tọ́ sí ọ jùlọ (lórí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ wọ̀nyẹn). (Ìyẹn) ló sì tọ́ sí ọ jùlọ.
75:35 Lẹ́yìn náà, (Iná) ló tọ́ sí ọ jùlọ (ní ọ̀run). (Ìyẹn) ló sì tọ́ sí ọ jùlọ.
75:36 Ṣé ènìyàn lérò pé A máa fi òun sílẹ̀ lásán ni?
75:37 Ṣé kò ti jẹ́ àtọ̀ mọnī tí wọ́n dà jáde sínú àpòlùkẹ́ ni?
75:38 Lẹ́yìn náà, ó di ẹ̀jẹ̀ dídì. (Allāhu) sì ṣẹ̀dá (rẹ̀). Ó sì ṣe é tó dọ́gba jálẹ̀ léèyàn.
75:39 (Allāhu) sì ṣe ìran méjì jáde láti ara rẹ̀, akọ àti abo.
75:40 Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó ṣe ìyẹn kò níí ní agbára láti jí àwọn òkú dìde bí?