36:1
Yā sīn (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1]
36:2
(Allāhu) fi Al-Ƙur’ān tí ó kún fún ọgbọ́n búra.[1]
36:3
Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.
36:4
(O) wà lórí ọ̀nà tààrà (’Islām).
36:5
(Al-Ƙur’ān jẹ́) ìmísí tó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run
36:6
nítorí kí o lè ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn kan, (àwọn) tí wọn kò ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn bàbá wọn rí. Nítorí náà, afọ́núfọ́ra sì ni wọ́n (nípa ìmọ̀nà).[1]
36:7
Dájúdájú ọ̀rọ̀ náà ti kò lé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn lórí; wọn kò sì níí gbàgbọ́.
36:8
Dájúdájú Àwa ti kó ẹ̀wọ̀n sí wọn lọ́rùn (mọ́ ọwọ́ wọn). Ó sì ga dé àgbọ̀n (wọn). Wọ́n sì gà wọ́n lọ́rùn sókè.
36:9
Àti pé Àwa fi gàgá kan síwájú wọn, gàgá kan sẹ́yìn wọn; A bò wọ́n lójú, wọn kò sì ríran.
36:10
Bákan náà ni fún wọn, yálà o kìlọ̀ fún wọn tàbí o kò kìlọ̀ fún wọn; wọn kò níí gbàgbọ́.[1]
36:11
Ẹni tí ìkìlọ̀ rẹ (máa wúlò fún) ni ẹni tí ó tẹ̀lé Ìrántí (al-Ƙur’ān), tí ó sì páyà Àjọkẹ́-ayé ní ìkọ̀kọ̀. Nítorí náà, fún un ní ìró ìdùnnú nípa àforíjìn àti ẹ̀san alápọ̀n-ọ́nlé.
36:12
Dájúdájú Àwa l’À ń sọ àwọn òkú di alàyè. A sì ń ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n tì síwájú àti orípa (iṣẹ́ ọwọ́) wọn. Gbogbo n̄ǹkan ni A ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú tírà kan tó yanjú.
36:13
Fi àpèjúwe kan lélẹ̀ fún wọn nípa àwọn ará ìlú kan nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ wá bá wọn.
36:14
(Rántí) nígbà tí A rán Òjíṣẹ́ méjì níṣẹ́ sí wọn. Wọ́n pe àwọn méjèèjì ní òpùrọ́. A sì fi ẹnì kẹta ró àwọn méjèèjì lágbára. Wọ́n sì sọ pé: “Dájúdájú àwa ni Òjíṣẹ́ tí Wọ́n rán níṣẹ́ si yín.”[1]
36:15
Wọ́n wí pé: “Ẹ̀yin kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú tiwa. Àjọkẹ́-ayé kò sì sọ n̄ǹkan kan kalẹ̀. Ẹ̀yin kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe òpùrọ́.”
36:16
Wọ́n sọ pé: “Olúwa wa mọ̀ pé dájúdájú àwa ni Òjíṣẹ́ tí Wọ́n rán níṣẹ́ si yín.
36:17
Kò sì sí ojúṣe kan fún wa bí kò ṣe ìkéde (ẹ̀sìn) tó yanjú.”
36:18
Wọ́n wí pé: “Dájúdájú àwa rí àmì aburú lára yín. Tí ẹ kò bá jáwọ́ (níbi ìpèpè yín), dájúdájú a máa sọ yín lókò pa. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro yó sì jẹ yín láti ọ̀dọ̀ wa.”
36:19
Wọ́n sọ pé: “Àmì aburú yín ń bẹ pẹ̀lú yín. Ṣé nítorí pé wọ́n ṣe ìṣítí fún yín (l’ẹ fi rí àmì aburú lára wa)? Kò rí bẹ́ẹ̀! Ìjọ alákọyọ ni yín ni.”
36:20
Ọkùnrin kan sáré dé láti òpin ìlú náà, ó wí pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ tẹ̀lé àwọn Òjíṣẹ́ náà.
36:21
Ẹ tẹ̀lé ẹni tí kò bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín. Olùmọ̀nà sì ni wọ́n.
36:22
Kí ni ó máa mú mi tí èmi kò fi níí jọ́sìn fún Ẹni tí Ó pilẹ̀ ẹ̀dá mi? Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí.
36:23
Ṣé kí èmi sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu ni? Tí Àjọkẹ́-ayé bá fẹ́ fi ìnira kàn mí, ìṣìpẹ̀ wọn kò lè rọ̀ mí lọ́rọ̀ kiní kan, wọn kò sì lè gbà mí là.
36:24
(Bí èmi kò bá jọ́sìn fún Allāhu) nígbà náà dájúdájú mo ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.
36:25
Dájúdájú èmi gbàgbọ́ nínú Olúwa Ẹlẹ́dàá yín. Nítorí náà, ẹ gbọ́ mi.” (Àwọn aláìgbàgbọ́ sì pa onígbàgbọ́ òdodo yìí.)
36:26
(Àwọn mọlāika) wọ́n sọ pé: “Wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra.” Ó sọ pé: “(Ó mà ṣe o!) Àwọn ènìyàn mi ìbá ní ìmọ̀
36:27
nípa bí Olúwa mi ṣe foríjìn mí àti (bí) Ó ṣe fi mí sí ara àwọn alápọ̀n-ọ́nlé (wọn ìbá ronú pìwàdà).”
36:28
A kò sọ ọmọ ogun kan kalẹ̀ lé àwọn ènìyàn rẹ̀ lórí láti sánmọ̀ lẹ́yìn rẹ̀. A kò sì sọ (mọlāika kan) kalẹ̀ (fún ìparun wọn).
36:29
(Ìparun wọn) kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe igbe ẹyọ kan; nígbà náà ni wọ́n di òkú kalẹ̀.
36:30
Àbámọ̀ mà ni fún àwọn ẹrúsìn náà (nígbà tí wọ́n bá fojú ara wọn rí Iná); òjíṣẹ́ kan kò níí wá bá wọn àyàfi kí wọ́n máa fi ṣe yẹ̀yẹ́.
36:31
Ṣé wọn kò wòye pé mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn? (Ṣé wọn kò wòye pé) dájúdájú wọn kò padà sí ọ̀dọ̀ wọn mọ́ (nílé ayé) ni?
36:32
Dájúdájú gbogbo wọn pátápátá sì ni (àwọn mọlāika) máa kó wá sí ọ̀dọ̀ Wa.
36:33
Àmì ni òkú ilẹ̀[1] jẹ́ fún wọn. A sọ ọ́ di ààyè. A sì mú èso jáde láti inú rẹ̀. Wọ́n sì ń jẹ nínú rẹ̀.
36:34
A tún ṣe àwọn ọgbà dàbínù àti àjàrà sórí ilẹ̀. A sì mú àwọn odò ìṣẹ́lẹ̀rú ṣàn láti inú rẹ̀
36:35
nítorí kí wọ́n lè jẹ nínú èso rẹ̀ àti èyí tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe![1] Ṣé wọn kò níí dúpẹ́ ni?
36:36
Mímọ́ ni fún Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan ní oríṣiríṣi nínú ohun tí ilẹ̀ ń hù jáde àti nínú ẹ̀mí ara wọn àti nínú ohun tí wọn kò mọ̀.[1]
36:37
Àmì kan ni òru jẹ́ fún wọn, tí À ń yọ ọ̀sán jáde láti inú rẹ̀. Nígbà náà (tí A bá yọ ọ́ tán) wọn yóò tún wà nínú òkùnkùn (alẹ́ mìíràn).[1]
36:38
Àti pé òòrùn yóò máa rìn lọ sí àyè rẹ̀. Ìyẹn ni ètò (ti) Alágbára, Onímọ̀.
36:39
Òṣùpá náà, A ti ṣe òdíwọ̀n àwọn ibùsọ̀ fún un (tí ó ti ma máa tóbi sí i) títí ó máa fi padà dà bíi àran ọ̀pẹ tó ti pẹ́ (gbígbẹ).
36:40
Kò yẹ fún òòrùn láti lo àsìkò òṣùpá. Kò sì yẹ fún alẹ́ láti lo àsìkò ọ̀sán. Ìkọ̀ọ̀kan wà ní òpópónà róbótó tó ń tọ̀.
36:41
Àmì kan tún ni fún wọn pé, dájúdájú Àwa gbé àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn gun ọkọ̀ ojú-omi tó kún kẹ́kẹ́.
36:42
A tún ṣẹ̀dá (òmíràn) fún wọn nínú irú rẹ̀ tí wọn yóò máa gún.[1]
36:43
Tí A bá fẹ́ Àwa ìbá tẹ̀ wọ́n rì sínú omi. Kò níí sí olùrànlọ́wọ́ kan fún wọn. Wọn kò sì níí gbà wọ́n là.
36:44
Àfi (kí Á fi) ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa (yọ wọ́n jáde, kí A sì tún fún wọn ní) ìgbádùn ayé títí di ìgbà díẹ̀.
36:45
(Wọ́n máa gbúnrí) nígbà tí A bá sọ fún wọn pé: “Ẹ ṣọ́ra fún ohun tó wà níwájú yín[1] àti ohun tó wà lẹ́yìn yín² nítorí kí A lè kẹ yín.”
36:46
Àti pé āyah kan nínú àwọn āyah Olúwa wọn kò níí wá bá wọn àfi kí wọ́n máa gbúnrí kúrò níbẹ̀.
36:47
Nígbà tí A bá sì sọ fún wọn pé: “Ẹ ná nínú ohun tí Allāhu ṣe ní arísìkí fún yín.”, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yóò wí fún àwọn tó gbàgbọ́ pé: “Ṣé kí á bọ́ ẹni tí (ó jẹ́ pé) Allāhu ìbá fẹ́ ìbá bọ́ ọ (àmọ́ kò bọ́ ọ. Àwa náà kò sì níí bá A bọ́ ọ)?” Kí ni ẹ̀yin bí kò ṣe pé (ẹ wà) nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.
36:48
Wọ́n ń wí pé: “Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”
36:49
Wọn kò retí kiní kan bí kò ṣe igbe ẹyọ kan ṣoṣo tí ó máa gbá wọn mú nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àríyànjiyàn lọ́wọ́.
36:50
Nígbà náà, wọn kò níí lè sọ àsọọ́lẹ̀ kan. Wọn kò sì níí lè padà sí ọ̀dọ̀ ará ilé wọn.
36:51
Wọ́n á sì fọn fèrè oníwo fún àjíǹde, nígbà náà ni wọn yóò máa sáré jáde láti inú sàréè wá sí ọ̀dọ̀ Olúwa wọn.
36:52
Wọ́n á wí pé: “Ègbé wa ò! Ta ni ó ta wá jí láti ojú oorun wa?” Èyí ni n̄ǹkan tí Àjọkẹ́-ayé ṣe ní àdéhùn. Àwọn Òjíṣẹ́ sì ti sọ òdodo (nípa rẹ̀).
36:53
Kò jẹ́ kiní kan tayọ igbe ẹyọ kan ṣoṣo. Nígbà náà ni (àwọn mọlāika) yóò kó gbogbo wọn wá sí ọ̀dọ̀ Wa.
36:54
Nítorí náà, ní òní wọn kò níí ṣe àbòsí kiní kan fún ẹ̀mí kan. A kò sì níí san yín ní ẹ̀san àfi ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
36:55
Dájúdájú ní òní, àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra yóò kún fún ìgbádùn.
36:56
Àwọn àti àwọn ìyàwó wọn yóò wà lábẹ́ àwọn ibòji, wọn yó sì rọ̀gbọ̀kú sórí àwọn ibùsùn.
36:57
Èso wà nínú rẹ̀ fún wọn. Ohun tí wọ́n yóò máa bèèrè fún tún wà fún wọn pẹ̀lú.
36:58
Àlàáfíà ni ọ̀rọ̀ tí ó má máa wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
36:59
Ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ bọ́ sí ọ̀tọ̀ ní òní.
36:60
Ẹ̀yin ọmọ (Ànábì) Ādam, ṣe Èmi kò ti pa yín ní àṣẹ pé, ẹ kò gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún aṣ-Ṣaetọ̄n? Dájúdájú òun ni ọ̀tá pọ́nńbélé fún yín.
36:61
Àti pé kí ẹ jọ́sìn fún Mi. Èyí ni ọ̀nà tààrà.
36:62
Àti pé (aṣ-Ṣaetọ̄n) kúkú ti ṣi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ẹ̀dá lọ́nà nínú yín. Ṣé ẹ kò níí ṣe làákàyè ni?
36:63
Èyí ni iná Jahanamọ tí À ń ṣe ní àdéhùn fún yín.
36:64
Ẹ wọ inú rẹ̀ ní òní nítorí pé, ẹ̀yin jẹ́ aláìgbàgbọ́.
36:65
Ní òní, A máa di ẹnu wọn pa. Àwọn ọwọ́ wọn yó sì máa bá Wa sọ̀rọ̀. Àwọn ẹsẹ̀ wọn yó sì máa jẹ́rìí sí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
36:66
Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́, Àwa ìbá fọ́ wọn lójú, wọn ìbá sì yára wá si ojú ọ̀nà, báwo ni wọ́n ṣe máa ríran ná?
36:67
Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́, Àwa ìbá yí wọn padà sí ẹ̀dá mìíràn nínú ibùgbé wọn. Wọn kò sì níí lágbára láti lọ síwájú. Wọn kò sì níí padà sẹ́yìn.
36:68
Ẹnikẹ́ni tí A bá fún ní ẹ̀mí gígùn lò, A óò sọ ẹ̀dá rẹ̀ di ọ̀lẹ, ṣé wọn kò níí ṣe làákàyè ni!
36:69
A kò kọ́ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ní ewì. Kò yẹ ẹ́ (kò sì rọ̀ ọ́ lọ́rùn láti kéwì). Kí ni ohun (tí A fi ránṣẹ́ sí i) bí kò ṣe ìrántí àti al-Ƙur’ān pọ́nńbélé
36:70
nítorí kí ó lè ṣèkìlọ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ alààyè àti nítorí kí ọ̀rọ̀ náà lè kò lórí àwọn aláìgbàgbọ́.
36:71
Ṣé wọn kò wòye pé dájúdájú Àwa l’A ṣẹ̀dá nínú ohun tí A fi ọwọ́ Wa ṣe (tí ó jẹ́) àwọn ẹran-ọ̀sìn fún wọn? Wọ́n sì ní ìkápá lórí wọn.
36:72
A tẹ̀ wọ́n lórí ba fún wọn; wọ́n ń gùn nínú wọn, wọ́n sì ń jẹ nínú wọn.
36:73
Àwọn àǹfààní àti ohun mímu tún wà fún wọn nínú rẹ̀. Ṣé wọn kò níí dúpẹ́ ni?
36:74
Wọ́n sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu nítorí kí wọ́n lè ṣàrànṣe fún wọn!
36:75
Wọn kò sì lè ṣe àrànṣe fún wọn; ṣebí àwọn òrìṣà ni ọmọ ogun tí (àwọn mọlāika) máa kó wá sínú Iná fún àwọn abọ̀rìṣà (láti fi jẹ wọ́n níyà).[1]
36:76
Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọn bà ọ́ nínú jẹ́. Dájúdájú Àwa mọ ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣàfi hàn rẹ̀.
36:77
Ṣé ènìyàn kò wòye pé dájúdájú Àwa l’A ṣẹ̀dá rẹ̀ láti inú àtọ̀? (Ṣebí lẹ́yìn) ìgbà náà l’ó di alátakò pọ́nńbélé.
36:78
Àti pé ó fi àkàwé lélẹ̀ nípa Wa.[1] Ó sì gbàgbé ìṣẹ̀dá rẹ̀. Ó wí pé: “Ta ni Ó máa sọ egungun di alààyè nígbà tí ó ti kẹfun?”
36:79
Sọ pé: “Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ nígbà àkọ́kọ́ l’Ó máa sọ ọ́ di alààyè. Òun sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo ẹ̀dá.
36:80
(Òun ni) Ẹni tí Ó mú iná jáde fún yín láti ara igi tútù. Ẹ sì ń fi dáná.
36:81
Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò ní agbára láti dá irú wọn (mìíràn) bí? Bẹ́ẹ̀ ni (Ó ní agbára). Òun sì ni Ẹlẹ́dàá, Onímọ̀.
36:82
Àṣẹ Rẹ̀ nígbà tí Ó bá gbèrò kiní kan ni pé, Ó máa sọ fún un pé “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.
36:83
Nítorí náà, mímọ́ ni fún Ẹni tí ìjọba gbogbo n̄ǹkan wà ní ọwọ́ Rẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí.