al-Qamar (القَمَر)

Yoruba:Mikail - Yoruba:Mikail

Chapter 54 • 55 verses • Meccan

← Previous Chapter Next Chapter →
54:1 Àkókò náà súnmọ́. Òṣùpá sì là pẹrẹgẹdẹ (sí méjì).[1]
54:2 Tí wọ́n bá rí àmì kan, wọ́n máa gbúnrí. Wọn yó sí wí pé: “Idán kan tó máa parẹ́ (ni èyí).”[1]
54:3 Wọ́n pè é ní irọ́. Wọ́n sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn. Gbogbo iṣẹ́ ẹ̀dá sì máa jókòó tì í lọ́rùn. [1]
54:4 Dájúdájú wáàsí tí ó ń kọ aburú[1] wà nínú àwọn ìró tó dé bá wọn.
54:5 (al-Ƙur’ān sì ni) ọgbọ́n tó péye pátápátá; ṣùgbọ́n àwọn ìkìlọ̀ náà kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀.
54:6 Ṣẹ́rí kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn. Ní ọjọ́ tí olùpèpè yóò pèpè fún kiní kan tí ẹ̀mí kórira (ìyẹn, Àjíǹde),
54:7 Ojú wọn máa wálẹ̀ ní ti àbùkù. Wọn yó sì máa jáde láti inú sàréè bí ẹni pé eṣú tí wọ́n fọ́nká síta ni wọ́n.
54:8 Wọn yó sì máa yára lọ sí ọ̀dọ̀ olùpèpè náà. Àwọn aláìgbàgbọ́ yó sì wí pé: “Èyí ni ọjọ́ ìṣòro.”
54:9 Ìjọ (Ànábì) Nūh pe òdodo ní irọ́ ṣíwájú wọn. Nígbà náà, wọ́n pe ẹrúsìn Wa ní òpùrọ́. Wọ́n sì wí pé: “Wèrè ni.” Wọ́n sì kọ̀ fún un pẹ̀lú ohùn líle.[1]
54:10 Nítorí náà, ó pe Olúwa rẹ̀ pé: “Dájúdájú wọ́n ti borí mi. Bá mi gbẹ̀san.”
54:11 Nítorí náà, A ṣí àwọn ìlẹ̀kùn sánmọ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú omi tó lágbára.
54:12 A tún mú àwọn odò ṣàn jáde láti inú ilẹ̀. Omi (sánmọ̀) pàdé (omi ilẹ̀) pẹ̀lú àṣẹ tí A ti kọ (lé wọn lórí).
54:13 A sì gbé (Ànábì) Nūh gun ọkọ̀ onípákó, ọkọ̀ eléṣòó,
54:14 tí ó ń rìn (lórí omi) lójú Wa. (Ó jẹ́) ẹ̀san nítorí ẹni tí wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀.
54:15 Dájúdájú A ṣẹ́ ẹ kù (tí A fi ṣe) àmì. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
54:16 Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?
54:17 Dájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
54:18 Ìran ‘Ād pé òdodo ní irọ́. Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?
54:19 Dájúdájú Àwa rán atẹ́gùn líle sí wọn ní ọjọ́ burúkú kan tó ń tẹ̀ síwájú.[1]
54:20 Ó ń fa àwọn ènìyàn tu bí ẹni pé kùkùté igi ọ̀pẹ tí wọ́n fà tu tegbòtegbò ni wọ́n.
54:21 Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?
54:22 Dájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
54:23 Ìjọ Thamūd pe àwọn ìkìlọ̀ ní irọ́.
54:24 Wọ́n wí pé: “Ṣé abara kan, ẹnì kan ṣoṣo nínú wa ni a óò máa tẹ̀lé. (Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀) nígbà náà dájúdájú àwa ti wà nínú ìṣìnà àti wàhálà.
54:25 Ṣé òun ni wọ́n sọ tírà ìrántí kalẹ̀ fún láààrin wa? Rárá o, òpùrọ́ onígbèéraga ni.”
54:26 Ní ọ̀la ni wọn yóò mọ ta ni òpùrọ́ onígbèéraga.
54:27 Dájúdájú Àwa máa rán abo ràkúnmí sí wọn; (ó máa jẹ́) àdánwò fún wọn. Nítorí náà, máa wò wọ́n níran ná, kí o sì ṣe sùúrù.[1]
54:28 Kí o sì fún wọn ní ìró pé dájúdájú pípín ni omi láààrin wọn. Gbogbo ìpín omi sì wà fún ẹni tí ó bá kàn láti wá sí odò.
54:29 Wọ́n pe ẹni wọn. Ó yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ nawọ́ mú (ràkúnmí náà mọ́lẹ̀). Ó sì pa á.
54:30 Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?
54:31 Dájúdájú Àwa rán igbe kan ṣoṣo sí wọn. Wọ́n sì dà bí koríko gbígbẹ tí àgbẹ̀ dáná sun.
54:32 Dájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
54:33 Ìjọ Lūt pe àwọn ìkìlọ̀ ní irọ́.
54:34 Dájúdájú Àwa fi òkúta iná ránṣẹ́ sí wọn àfi ará ilé Lūt, tí A gbàlà ní àsìkò sààrì.
54:35 (Ó jẹ́) ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa. Báyẹn ni A ṣe ń san ẹ̀san fún ẹni tó bá dúpẹ́ (fún Wa).
54:36 Ó kúkú fi ìgbámú Wa ṣe ìkìlọ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ja àwọn ìkìlọ̀ níyàn.
54:37 Wọ́n kúkú làkàkà lọ́dọ̀ rẹ̀ láti bá àwọn aléjò rẹ̀ ṣèbàjẹ́. Nítorí náà, A fọ́ ojú wọn. Ẹ tọ́ ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi wò.
54:38 Àti pé dájúdájú ìyà gbére ni wọ́n mọ́júmọ́ sínú rẹ̀ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù.
54:39 Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi wò.
54:40 Dájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
54:41 Dájúdájú àwọn ìkìlọ̀ dé bá àwọn ènìyàn Fir‘aon.
54:42 Wọ́n pe gbogbo àwọn āyah Wa ní irọ́ pátápátá. A sì gbá wọn mú ní ìgbámú (tí) Alágbára, Olùkápá (máa ń gbá ẹ̀dá mú).
54:43 Ṣé àwọn aláìgbàgbọ́ (nínú) yín l’ó lóore ju àwọn wọ̀nyẹn (tí wọ́n ti parẹ́ bọ́ sẹ́yìn) ni tàbí ẹ̀yin ní ìmóríbọ́ kan nínú ìpín-ìpín Tírà (pé ẹ̀yin kò níí jìyà)?
54:44 Tàbí wọ́n ń wí pé: “Àwa wà papọ̀ tí a óò ranra wa lọ́wọ́ láti borí (Òjíṣẹ́)”
54:45 A máa fọ́ àkójọ náà lógun. Wọn sì máa fẹsẹ̀ fẹ́ẹ lójú ogun.
54:46 Àmọ́ sá, Àkókò náà ni ọjọ́ àdéhùn wọn. Àkókò náà burú jùlọ. Ó sì korò jùlọ.
54:47 Dájúdájú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ wà nínú ìṣìnà àti wàhálà.
54:48 Ní ọjọ́ tí A óò dojú wọn bolẹ̀ wọ inú Iná, (A ó sì sọ pé): Ẹ tọ́ ìfọwọ́bà Iná wò.
54:49 Dájúdájú A ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan pẹ̀lú kádàrá.
54:50 Àṣẹ Wa (fún mímú n̄ǹkan bẹ) kò tayọ (àṣẹ) ẹyọ kan ṣoṣo gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ́jú.[1]
54:51 Àti pé dájúdájú A ti pa àwọn irú yín rẹ́. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
54:52 Gbogbo n̄ǹkan tí wọ́n ṣe níṣẹ́ sì wà nínú ìpín-ìpín tírà.
54:53 Àti pé gbogbo n̄ǹkan kékeré àti n̄ǹkan ńlá (tí wọ́n ṣe) wà ní àkọsílẹ̀.
54:54 Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) yóò wà nínú àwọn Ọgbà (Ìdẹ̀ra) pẹ̀lú àwọn odò (tó ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀).
54:55 Ní ibùjókòó òdodo nítòsí Ọba Alágbára Olùkápá.