92:1
Allāhu fi alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú búra.
92:2
Ó tún fi ọ̀sán nígbà tí (ọ̀sán) bá pọ́n búra.
92:3
Ó tún fi Ẹni tí Ó dá akọ àti abo búra.[1]
92:4
Dájúdájú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni iṣẹ́ yín.
92:5
Ní ti ẹni tí ó bá tọrẹ, tí ó sì bẹ̀rù (Allāhu),
92:6
(tí) ó tún pe ẹ̀san rere (Ọgbà Ìdẹ̀ra) ní òdodo,
92:7
A sì máa ṣe iṣẹ́ rere ní ìrọ̀rùn fún un.
92:8
Ní ti ẹni tí ó bá yahun, tí ó sì rí ara rẹ̀ lẹ́ni tó rọrọ̀ tayọ ẹ̀san ọ̀run,
92:9
(tí) ó tún pe ẹ̀san rere (Ọgbà Ìdẹ̀ra) ní irọ́,
92:10
A sì máa ṣe iṣẹ́ aburú ní ìrọ̀rùn fún un.
92:11
Dúkìá rẹ̀ kò sì níí rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ nígbà tí ó bá parun, tí ó já bọ́ (sínú Iná).
92:12
Dájúdájú tiWa ni (láti ṣàlàyé) ìmọ̀nà.
92:13
Àti pé dájúdájú tiWa ni ọ̀run àti ayé.
92:14
Nítorí náà, Mo ti fi Iná tó ń jò fòfò kìlọ̀ fún yín.
92:15
Kò sí ẹni tí ó máa wọ inú rẹ̀ àfi olórí burúkú,
92:16
ẹni tí ó pe òdodo ní irọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i.
92:17
Wọ́n sì máa gbé (Iná) jìnnà sí olùbẹ̀rù (Allāhu),
92:18
ẹni tó ń fi dúkìá rẹ̀ tọrẹ, tí ó ń ṣàfọ̀mọ́ (rẹ̀).
92:19
Kò sì sí oore ìdẹ̀ra kan tí (ó ní lọ́kàn) láti gbà ní ẹ̀san ní ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni,
92:20
bí kò ṣe pé láti fi wá ojú rere Olúwa rẹ̀, Ẹni Gíga jùlọ.
92:21
Láìpẹ́ ó sì máa yọ́nú (sí ẹ̀san rere rẹ̀).