ad-Dhuha (الضُّحَىٰ)

Yoruba:Mikail - Yoruba:Mikail

Chapter 93 • 11 verses • Meccan

← Previous Chapter Next Chapter →
93:1 Allāhu fi ìyálẹ̀ta búra.
93:2 Ó tún fi alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú búra.
93:3 Olúwa rẹ kò pa ọ́ tì, kò sì bínú sí ọ.
93:4 Dájúdájú ọ̀run lóore fún ọ ju ayé.
93:5 Dájúdájú láìpẹ́ Olúwa rẹ máa fún ọ ní (oore púpọ̀ ní ọ̀run). Nítorí náà, o sì máa yọ́nú sí i.
93:6 Ṣé (Allāhu) kò rí ọ ní ọmọ-òrukàn ni? Ó sì fún ọ ní ibùgbé.
93:7 Ó sì rí ọ ní aláìmọ̀nà (ìyẹn ṣíwájú ìsọ̀kalẹ̀ ìmísí). Ó sì fi ọ̀nà mọ̀ ọ́.[1]
93:8 Ó tún rí ọ ní aláìní, Ó sì rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀.
93:9 Nítorí náà, ní ti ọmọ-òrukàn, má ṣe jẹ gàba (lé e lórí).
93:10 Ní ti alágbe, má sì ṣe jágbe (mọ́ ọn).
93:11 Ní ti ìdẹ̀ra Olúwa rẹ, sọ ọ́ jáde.