al-Inshirah (الشَّرْح)

Yoruba:Mikail - Yoruba:Mikail

Chapter 94 • 8 verses • Meccan

← Previous Chapter Next Chapter →
94:1 Ṣé A kò ṣípayá igbá-àyà rẹ fún ọ bí?
94:2 A sì gbé ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò lọ́rùn rẹ,
94:3 èyí tí ó wọ̀ ọ́ lọ́rùn.[1]
94:4 A sì gbé ìrántí orúkọ rẹ ga fún ọ.
94:5 Nítorí náà, dájúdájú ìdẹ̀kùn wà lẹ́yìn ìnira.
94:6 Dájúdájú ìdẹ̀kùn wà lẹ́yìn ìnira sẹ́.
94:7 Nítorí náà, nígbà tí o bá bùṣe (lórí ohun tí ó jẹmọ́ táyé), gbìyànjú (dáadáa lórí ìjọ́sìn).
94:8 Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì ni kí o ṣojú kòkòrò oore sí.