at-Tin (التِّين)

Yoruba:Mikail - Yoruba:Mikail

Chapter 95 • 8 verses • Meccan

← Previous Chapter Next Chapter →
95:1 Allāhu fi èso tīn àti èso zaetūn búra.
95:2 Ó tún fi àpáta Sīnīn búra.
95:3 Ó tún fi ìlú ìfàyàbalẹ̀ yìí búra.
95:4 Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn pẹ̀lú ìrísí tó dára jùlọ.
95:5 Lẹ́yìn náà, A máa dá a padà sí ìsàlẹ̀ pátápátá (nínú Iná).
95:6 Àyàfi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Nítorí náà, ẹ̀san tí kò níí pin (tí kò níí pẹ̀dín) ń bẹ fún wọn.
95:7 Ta l’ó tún ń pè ọ́ ní òpùrọ́ nípa Ọjọ́ ẹ̀san lẹ́yìn (ọ̀rọ̀ yìí)?
95:8 Ṣé Allāhu kọ́ ni Ẹni t’Ó mọ ẹ̀jọ́ dá jùlọ nínú àwọn adájọ́ ni?