73:1
Ìwọ olùdaṣọbora.
73:2
Dìde (kírun) ní òru àyàfi fún ìgbà díẹ̀ (ni kí o fi sùn nínú òru rẹ).
73:3
Lo ìlàjì rẹ̀ tàbí dín díẹ̀ kù nínú rẹ̀.
73:4
Tàbí fi kún un. Kí o sì ké al-Ƙur’ān pẹ̀lú pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́.[1]
73:5
Dájúdájú Àwa máa gbé ọ̀rọ̀ tó lágbára fún ọ.
73:6
Dájúdájú ìdìde kírun lóru, ó wọnú ọkàn jùlọ, ó sì dára jùlọ fún kíké (al-Ƙur’ān).
73:7
Dájúdájú iṣẹ́ púpọ̀ wà fún ọ ní ọ̀sán.
73:8
Rántí orúkọ Olúwa rẹ. Kí o sì da ọkàn kọ Ọ́ pátápátá.
73:9
Olúwa ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn, kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àfi Òun. Nítorí náà, mú Un ní Aláfẹ̀yìntì.
73:10
Kí o sì ṣe sùúrù lórí ohun tí wọ́n ń wí. Pa wọ́n tì ní ìpatì tó rẹwà.
73:11
Fi Mí dá àwọn olùpe-òdodo-nírọ́, àwọn ọlọ́rọ̀. Kí o sì lọ́ra fún wọn fún ìgbà díẹ̀.
73:12
Dájúdájú ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ àti Iná Jẹhīm ń bẹ lọ́dọ̀ Wa.
73:13
Oúnjẹ háfunháfun àti ìyà ẹlẹ́ta-eléro (tún wà fún wọn).
73:14
Ní ọjọ́ tí ilẹ̀ àti àwọn àpáta yóò máa mì tìtì. Àwọn àpáta sì máa di yanrìn tí wọ́n kójọ tí wọ́n túká.
73:15
Dájúdájú Àwa rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ si yín (tí ó jẹ́) olùjẹ́rìí lórí yín gẹ́gẹ́ bí A ṣe rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ sí Fir‘aon.
73:16
Ṣùgbọ́n Fir‘aon yapa Òjíṣẹ́ náà. A sì gbá a mú ní ìgbámú líle.
73:17
Tí ẹ̀yin bá ṣàì gbàgbọ́, báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe bẹ̀rù ọjọ́ kan tó máa mú àwọn ọmọdé hewú?
73:18
Sánmọ̀ sì máa fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nínú rẹ̀. Àdéhùn Rẹ̀ jẹ́ ohun tí ó máa ṣẹ.
73:19
Dájúdájú èyí ni ìrántí. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mú ojú ọ̀nà kan tọ̀ dé ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀.
73:20
Dájúdájú Olúwa rẹ mọ̀ pé dájúdájú ìwọ ń dìde kírun fún ohun tó kéré sí ìlàta méjì òru tàbí ìlàjì rẹ̀ tàbí ìlàta rẹ̀. Igun kan nínú àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ (náà ń ṣe bẹ́ẹ̀). Allāhu l’Ó ń ṣòdíwọ̀n òru àti ọ̀sán. Ó sì mọ̀ pé ẹ kò lè ṣọ́ ọ.1 Nítorí náà, Ó ti dá a padà sí fífúyẹ́ fún yín. Nítorí náà, ẹ ké ohun tí ó bá rọrùn (fún yín) nínú al-Ƙur’ān. Ó mọ̀ pé àwọn aláìsàn yóò wà nínú yín. Àwọn mìíràn sì ń rìrìn àjò lórí-ilẹ̀, tí wọ́n ń wá nínú oore Allāhu. Àwọn mìíràn sì ń jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu. Nítorí náà, ẹ ké ohun tí ó bá rọrùn (fún yín) nínú rẹ̀. Ẹ kírun (ọ̀ran-an-yàn). Ẹ yọ Zakāh. Kí ẹ sì yá Allāhu ní dúkìá tó dára. Ohunkóhun tí ẹ bá tì síwájú fún ẹ̀mí ara yín nínú ohun rere, ẹ̀yin yóò bá a lọ́dọ̀ Allāhu ní ohun rere àti ní ohun tí ó tóbi jùlọ ní ẹ̀san. Ẹ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.