100:1
Allāhu fi àwọn ẹṣin tó ń sáré tó ń mí hẹlẹhẹlẹ ní ojú-ogun búra.
100:2
Ó tún fi àwọn ẹṣin tí pátákò ẹsẹ̀ wọn ń ṣáná (níbi eré sísá) búra.
100:3
Ó tún fi àwọn ẹṣin tó ń kọlu ọ̀tá ẹ̀sìn ní òwúrọ̀ kùtùkùtù búra.
100:4
Wọ́n sì fi (pátákò ẹsẹ̀ wọn) tu eruku (ilẹ̀ ọ̀tá) sókè.
100:5
Wọ́n tún bẹ́ gìjà pẹ̀lú eruku ẹsẹ̀ wọn sáààrin àkójọ ọ̀tá.
100:6
Dájúdájú ènìyàn ni aláìmoore sí Olúwa rẹ̀.
100:7
Dájúdájú Allāhu sì ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórí ìyẹn.
100:8
Àti pé dájúdájú ènìyàn le gan-an níbi ìfẹ́ oore ayé.
100:9
Ṣé kò mọ̀ pé nígbà tí wọ́n bá tú ohun tó wà nínú sàréè jáde (fún àjíǹde),
100:10
tí wọ́n sì tú ohun tó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá síta pátápátá,
100:11
dájúdájú Olúwa wọn ni Alámọ̀tán nípa wọn ní Ọjọ́ yẹn?