al-Humazah (الهُمَزَة)

Yoruba:Mikail - Yoruba:Mikail

Chapter 104 • 9 verses • Meccan

← Previous Chapter Next Chapter →
104:1 Ègbé ni fún gbogbo abúnilójú-ẹni, abúnilẹ́yìn-ẹni,
104:2 ẹni tí ó kó dúkìá jọ, tí ó sì kà á lákàtúnkà (láì ná an fún ẹ̀sìn).
104:3 Ó ń lérò pé dájúdájú dúkìá rẹ̀ yóò mú un ṣe gbére (nílé ayé).
104:4 Rárá (kò rí bẹ́ẹ̀). Dájúdájú wọ́n máa kù ú lókò sínú Hutọmọh ni.
104:5 Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Hutọmọh?
104:6 (Òhun ni) Iná Allāhu tí wọ́n ń kò (tó ń jó geregere),
104:7 èyí tí ó máa jó (ẹ̀dá) wọ inú ọkàn lọ.
104:8 Dájúdájú wọ́n máa ti (àwọn ìlẹ̀kùn) Iná pa mọ́ wọn lórí pátápátá.
104:9 (Wọ́n máa wà) láààrin àwọn òpó kìrìbìtì gíga (nínú Iná).