at-Takathur (التَّكَاثُر)

Yoruba:Mikail - Yoruba:Mikail

Chapter 102 • 8 verses • Meccan

← Previous Chapter Next Chapter →
102:1 Wíwá oore ayé ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ fún ìyanràn ṣíṣe ti kó àìrójú fẹ́sìn ba yín
102:2 títí ẹ fi wọ inú sàréè.
102:3 Rárá (kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀, àmọ́) láìpẹ́ ẹ máa mọ̀.
102:4 Lẹ́yìn náà, ní ti òdodo, láìpẹ́ ẹ máa mọ̀.
102:5 Ní ti òdodo, tí ó bá jẹ́ pé ẹ ni ìmọ̀ àmọ̀dájú ni (ẹ̀yin ìbá tí ṣe bẹ́ẹ̀).
102:6 Dájúdájú ẹ máa rí iná Jẹhīm.
102:7 Lẹ́yìn náà, dájúdájú ẹ máa fi ojú rí i ní àrídájú.
102:8 Lẹ́yìn náà, dájúdájú ní ọjọ́ yẹn wọ́n máa bi yín léèrè nípa ìgbádùn (ayé yìí).