Saba` (سَبَأ)

Yoruba:Mikail - Yoruba:Mikail

Chapter 34 • 54 verses • Meccan

← Previous Chapter Next Chapter →
34:1 Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ ń jẹ́ tiRẹ̀. Àti pé tiRẹ̀ ni gbogbo ẹyìn ní ọ̀run. Òun sì ni Ọlọ́gbọ́n, Alámọ̀tán.
34:2 Ó mọ ohunkóhun tó ń wọnú ilẹ̀ àti ohunkóhun tó ń jáde látinú rẹ̀. (Ó mọ) ohunkóhun tó ń sọ̀kalẹ̀ látinú sánmọ̀ àti ohunkóhun tó ń gùnkè lọ sínú rẹ̀. Òun sì ni Àṣàkẹ́-ọ̀run, Aláforíjìn.
34:3 Àwọn aláìgbàgbọ́ wí pé: “Àkókò náà kò níí dé bá wa.” Sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Èmi fi Olúwa mi búra. Dájúdájú ó máa dé ba yín (láti ọ̀dọ̀) Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ (Ẹni tí) òdiwọ̀n ọmọ iná-igún kò pamọ́ fún nínú àwọn sánmọ̀ àti nínú ilẹ̀. (Kò sí n̄ǹkan tí ó) kéré sí ìyẹn tàbí tí ó tóbi (jù ú lọ) àfi kí ó wà nínú àkọsílẹ̀ tó yanjú.”
34:4 (Ó máa ṣẹlẹ̀) nítorí kí Allāhu lè san ẹ̀san fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n tún ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn wọ̀nyẹn ni àforíjìn àti èsè alápọ̀n-ọ́nlé ń bẹ fún.
34:5 Àwọn tó ṣe iṣẹ́ (burúkú) nípa àwọn āyah Wa, tí wọ́n ń dá àwọn ènìyàn ní agara (láti tẹ̀lé àwọn āyah Wa, tí wọ́n sì lérò pé àwọn máa mórí bọ́ lọ́dọ̀ Allāhu); àwọn wọ̀nyẹn, ìyà kan nínú ìyà ẹlẹ́ta-eléró ń bẹ fún wọn.
34:6 Àwọn tí A fún ní ìmọ̀ mọ̀ pé, èyí tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, òhun ni òdodo, àti pé ó ń ṣe ìtọ́sọ́nà sí ọ̀nà (Allāhu) Alágbára, Ẹlẹ́yìn.
34:7 Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: “Ṣé kí á tọ́ka yín sí ọkùnrin kan tí ó máa fún yín ní ìró pé nígbà tí wọ́n bá tú (ara) yín ká tán pátápátá (sínú erùpẹ̀, tí ẹ ti di erùpẹ̀), pé dájúdájú ẹ máa padà wà ní ẹ̀dá titun?
34:8 Ṣé ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu ni tàbí àlùjànnú ń bẹ lára rẹ̀ ni?” Rárá o! Àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́ ti wà nínú ìyà àti ìṣìnà tó jìnnà.
34:9 Ṣé wọn kò rí ohun tó ń bẹ níwájú wọn àti ohun tó ń bẹ lẹ́yìn wọn ní sánmọ̀ àti ilẹ̀? Tí A bá fẹ́, Àwa ìbá jẹ́ kí ilẹ̀ ri mọ́ wọn lẹ́sẹ̀, tàbí kí Á já apá kan nínú sánmọ̀ lulẹ̀ lé wọn lórí mọ́lẹ̀. Dájúdájú àmì kan wà nínú ìyẹn fún gbogbo ẹrúsìn, olùronúpìwàdà.
34:10 Dájúdájú A ti fún (Ànábì) Dāwūd ní oore àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Wa; Ẹ̀yin àpáta, ẹ ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú rẹ̀. (A pe) àwọn ẹyẹ náà (pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.) A sì rọ irin fún un.
34:11 (A sọ fún un) pé, ṣe àwọn ẹ̀wù irin tó máa bo ara dáadáa, ṣe òrùka fún ẹ̀wù irin náà níwọ̀n-níwọ̀n. Kí ẹ sì ṣe rere. Dájúdájú Èmi ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
34:12 Àti pé (A tẹ) atẹ́gùn lórí bá fún (Ànábì) Sulaemọ̄n, ìrìn oṣù kan ni ìrìn òwúrọ̀ rẹ̀, ìrìn oṣù kan sì ni ìrìn ìrọ̀lẹ́ rẹ̀[1]. A sì mú kí odò idẹ máa ṣàn nínú ilẹ̀ fún un. Ó sì wà nínú àwọn àlùjànnú, èyí tó ń ṣiṣẹ́ (fún un) níwájú rẹ̀ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Olúwa rẹ̀. Àti pé ẹni tí ó bá yẹ̀ kúrò níbi àṣẹ Wa nínú wọn, A máa fún un ní ìyà iná tó ń jó tọ́ wò.
34:13 Wọ́n ń ṣe iṣẹ́ tí ó bá fẹ́ fún un nípa mímọ àwọn ilé (ilé ìjọ́sìn àti ilé ìgbé), àwọn ère,[1] àwọn àwo tó jìn kòtò tó fẹ̀ bí àbàtಠàti àwọn ìkòkò tó rídìí múlẹ̀.³ Ẹ̀yin ènìyàn (Ànábì) Dāwūd, ẹ ṣiṣẹ́ ìdúpẹ́ (fún Allāhu). Díẹ̀ nínú àwọn ẹrúsìn Mi sì ni olùdúpẹ́.
34:14 Nígbà tí A pàṣẹ pé kí ikú pa (Ànábì) Sulaemọ̄n, kò sí ohun tí ó mú àwọn àlùjànnú mọ̀ pé ó ti kú bí kò ṣe kòkòrò inú ilẹ̀ kan tí ó jẹ ọ̀pá rẹ̀. Nígbà tí ó wó lulẹ̀, ó hàn kedere sí àwọn àlùjànnú pé tí ó bá jẹ́ pé àwọn ní ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ ni, àwọn ìbá tí wà nínú (iṣẹ́) ìyà tó ń yẹpẹrẹ ẹ̀dá.
34:15 Dájúdájú àmì kan wà fún àwọn Saba’ nínú ibùgbé wọn; (òhun ni) ọgbà oko méjì tó wà ní ọ̀tún àti ní òsì.[1] “Ẹ jẹ nínú arísìkí Olúwa yín. Kí ẹ sì dúpẹ́ fún Un.” Ìlú tó dára ni (ilẹ̀ àwọn Saba’. Allāhu sì ni) Olúwa Aláforíjìn.
34:16 Wọ́n gbúnrí (níbi ẹ̀sìn). Nítorí náà, A rán adágún odò tí wọ́n mọ odi yíká sí wọn. A sì pààrọ̀ oko wọn méjèèjì fún wọn pẹ̀lú oko èso méjì mìíràn tí ó jẹ́ oko èso tó korò, oko igi àti kiní kan nínú igi sidir díẹ̀.[1]
34:17 Ìyẹn ni A fi san wọ́n ní ẹ̀san nítorí pé, wọ́n ṣàì moore. Ǹjẹ́ A máa san ẹnì kan lẹ́san ìyà bí kò ṣe aláìmoore?
34:18 A sì fi àwọn ìlú kan tó wà ní gban̄gba sí ààrin ìlú tí A rán adágún odò sí[1] àti àwọn ìlú tí A fi ìbùkún sí. A sì ṣètò ibùsọ̀ níwọ̀n-níwọ̀n fún ìrìn-àjò ṣíṣe sínú àwọn ìlú náà.² Ẹ rìn lọ sínú wọn ní òru àti ní ojú ọjọ́ pẹ̀lú ìfàyàbalẹ̀.
34:19 (Àwọn ará ìlú Saba’) wí pé: “Olúwa wa, mú àwọn ìrìn-àjò wa láti ìlú kan sí ìlú mìíràn jìnnà síra wọn.” Wọ́n ṣe àbòsí sí ẹ̀mí ara wọn.[1] A sì sọ wọ́n di ìtàn. A tú wọn ká pátápátá (ìlú wọn di ahoro). Dájúdájú àwọn àmì kan wà nínú ìyẹn fún gbogbo onísùúrù, olùdúpẹ́.
34:20 Dájúdájú ’Iblīs ti sọ àbá-modá rẹ̀ di òdodo lórí wọn. Wọ́n sì tẹ̀lé e àfi igun kan nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
34:21 (’Iblīs) kò sì ní agbára kan lórí wọn bí kò ṣe pé kí A lè ṣàfi hàn ẹni tó gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́ kúrò lára ẹni tó wà nínú iyèméjì nípa rẹ̀. Olùṣọ́ sì ni Olúwa rẹ lórí gbogbo n̄ǹkan.
34:22 Sọ pé: “Ẹ pe àwọn tí ẹ sọ pé (wọ́n jẹ́ ọlọ́hun) lẹ́yìn Allāhu.” Wọn kò ní ìkápá òdiwọ̀n ọmọ-iná igún nínú àwọn sánmọ̀ tàbí nínú ilẹ̀. Wọn kò sì ní ìpín kan nínú méjèèjì. Àti pé kò sí olùrànlọ́wọ́ kan fún Allāhu láààrin wọn.
34:23 Ìṣìpẹ̀ kò sì níí ṣàǹfààní lọ́dọ̀ Allāhu àfi fún ẹni tí Ó bá yọ̀ǹda fún. (Inúfu-àyàfu ní àwọn olùṣìpẹ̀ àti àwọn olùṣìpẹ̀-fún máa wà) títí A óò fi yọ ìjáyà kúrò nínú ọkàn wọn. Wọ́n sì máa sọ (fún àwọn mọlāika) pé: “Kí ni Olúwa yín sọ (ní èsì ìṣìpẹ̀)?” Wọ́n máa sọ pé: “Òdodo l’Ó sọ (ìṣìpẹ̀ yin ti wọlé. Allāhu) Òun l’Ó ga, Ó tóbi.[1]
34:24 Sọ pé: “Ta ni Ó ń pèsè fún yín láti inú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?” Sọ pé: “Allāhu ni.” Dájúdájú àwa tàbí ẹ̀yin wà nínú ìmọ̀nà tàbí nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.[1]
34:25 Sọ pé: “Wọn kò níí bi yín léèrè nípa ẹ̀ṣẹ̀ tí a dá; wọn kò sì níí bi àwa náà nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”
34:26 Sọ pé: “Olúwa wa yóò kó wa jọ papọ̀. Lẹ́yìn náà, Ó máa fi òdodo ṣèdájọ́ láààrin wa. Òun sì ni Onídàájọ́, Onímọ̀.”
34:27 Sọ pé: “Ẹ fi hàn mí ná àwọn òrìṣà tí ẹ dàpọ̀ mọ́ Allāhu.” Rárá (kò ní akẹgbẹ́). Rárá sẹ́, Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
34:28 A kò rán ọ níṣẹ́ àfi sí gbogbo ènìyàn pátápátá; (o jẹ́) oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀ ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀.
34:29 Wọ́n ń wí pé: “Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”
34:30 Sọ pé: “Àdéhùn ọjọ́ kan ń bẹ fún yín, tí ẹ kò níí lè sún un ṣíwájú di àkókò kan, ẹ kò sì níí lè fà á sẹ́yìn.”[1]
34:31 Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: “A kò níí ní ìgbàgbọ́ nínú al-Ƙur’ān yìí àti èyí tó wá ṣíwájú rẹ̀.” Tí ó bá jẹ́ pé o bá rí wọn ni nígbà tí wọ́n bá dá àwọn alábòsí dúró níwájú Olúwa wọn, (o máa rí wọn tí) apá kan wọn yóò dá ọ̀rọ̀ náà padà sí apá kan; àwọn tí wọ́n sọ di ọ̀lẹ (nínú wọn) yóò wí fún àwọn tó ṣègbéraga (nínú wọn) pé: “Tí kì í bá ṣe ẹ̀yin ni, àwa ìbá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.”
34:32 Àwọn tó ṣègbéraga yó sì wí fún àwọn tí wọ́n sọ di ọ̀lẹ pé: “Ṣé àwa l’a ṣẹ yín lórí kúrò nínú ìmọ̀nà lẹ́yìn tí ó dé ba yín? Rárá o! Ọ̀daràn ni yín ni.”
34:33 Àwọn tí wọ́n sọ di ọ̀lẹ yó sì wí fún àwọn tó ṣègbéraga pé: “Rárá! Ète òru àti ọ̀sán (láti ọ̀dọ̀ yín ló kóbá wa) nígbà tí ẹ̀ ń pa wá ní àṣẹ pé kí á ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu, kí á sì sọ (àwọn kan) di ẹgbẹ́ Rẹ̀.” Wọ́n fi àbámọ̀ wọn pamọ́ nígbà tí wọ́n rí ìyà. A sì kó ẹ̀wọ̀n sí ọrùn àwọn tó ṣàì gbàgbọ́. Ṣé A óò san wọ́n ní ẹ̀san kan bí kò ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́?
34:34 Àti pé A kò rán olùkìlọ̀ kan sí ìlú kan àyàfi kí àwọn onígbẹdẹmukẹ ìlú náà wí pé: “Dájúdájú àwa ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n fi ran yín níṣẹ́.”
34:35 Wọ́n tún wí pé: “Àwa ní dúkìá àti ọmọ jù (yín lọ); wọn kò sì níí jẹ wá níyà.”
34:36 Sọ pé: “Dájúdájú Olúwa mi, Ó ń tẹ́ arísìkí sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹlòmíìràn), ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀.
34:37 Kì í ṣe àwọn dúkìá yín, kì í sì ṣe àwọn ọmọ yín ni n̄ǹkan tí ó máa mu yín súnmọ́ Wa pẹ́kípẹ́kí àfi ẹni tí ó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn wọ̀nyẹn ni ẹ̀san ìlọ́po wà fún nípa ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Wọn yó sì wà nínú àwọn ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì gíga (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra) lẹ́ni ìfàyàbalẹ̀.
34:38 Àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ (burúkú) nípa àwọn āyah Wa, tí wọ́n ń dá àwọn ènìyàn ní agara (láti tẹ̀lé àwọn āyah Wa, tí wọ́n sì lérò pé àwọn máa mórí bọ́ lọ́dọ̀ Allāhu); àwọn wọ̀nyẹn ni (àwọn mọlāika) máa kó wá sínú Iná.”
34:39 Sọ pé: “Dájúdájú Olúwa mi, Ó ń tẹ́ arísìkí[1] sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ fún ẹlòmíìràn. Àti pé ohunkóhun tí ẹ bá ná, Òun l’Ó máa fi (òmíràn) rọ́pò rẹ̀. Ó sì l’óore jùlọ nínú àwọn olùpèsè.”²
34:40 Ní ọjọ́ tí Allāhu yóò kó gbogbo wọn jọ pátápátá, lẹ́yìn náà Ó máa sọ fún àwọn mọlāika pé: “Ṣé ẹ̀yin ni àwọn wọ̀nyí ń jọ́sìn fún?”
34:41 Wọ́n á sọ pé: “Mímọ́ ni fún Ọ! Ìwọ ni Aláàbò wa, kì í ṣe àwọn. Rárá (wọn kò jọ́sìn fún wa). Àwọn àlùjànnú ni wọ́n ń jọ́sìn fún; ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni wọ́n gbàgbọ́ nínú àwọn àlùjànnú.
34:42 Nítorí náà, ní òní apá kan yín kò ní ìkápá àǹfààní, kò sì ní ìkápá ìnira fún apá kan. A sì máa sọ fún àwọn tó ṣàbòsí pé: “Ẹ tọ́ ìyà Iná tí ẹ̀ ń pè ní irọ́ wò.”
34:43 Àti pé nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa tó yanjú fún wọn, wọ́n á wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe ọkùnrin kan tí ó fẹ́ ṣẹ yín lórí kúrò níbi n̄ǹkan tí àwọn bàbá yín ń jọ́sìn fún.” Wọ́n tún wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe àdápa irọ́.” Àti pé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wí nípa òdodo nígbà tí ó dé bá wọn pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe idán pọ́nńbélé.”
34:44 A kò fún wọn ní àwọn tírà kan kan tí wọ́n ń kọ́ ẹ̀kọ́ nínú rẹ̀, A kò sì rán olùkìlọ̀ kan sí wọn ṣíwájú rẹ.[1]
34:45 Àwọn tó ṣíwájú wọn náà pe òdodo ní irọ́. (Ọwọ́ àwọn wọ̀nyí) kò sì tí ì tẹ ìdá kan ìdá mẹ́wàá nínú ohun tí A fún (àwọn tó ṣíwájú). Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n pe àwọn Òjíṣẹ́ Mi ní òpùrọ́. Báwo sì ni bí Mo ṣe (fi ìyà) kọ (aburú fún wọn) ti rí!
34:46 Sọ pé: “Ohun kan ṣoṣo ni mò ń ṣe wáàsí rẹ̀ fún yín pé, ẹ dúró nítorí ti Allāhu ní méjì àti ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn náà, kí ẹ ronú jinlẹ̀. Kò sí àlùjànnú kan kan lára ẹni yín. Kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀ fún yín ṣíwájú ìyà líle kan.”
34:47 Sọ pé: “Èmi kò bi yín léèrè owó-ọ̀yà kan, ẹ̀yin lẹ kúkú lowó yín. Kò sí owó ọ̀yà mi (lọ́dọ̀ ẹnì kan) àfi lọ́dọ̀ Allāhu. Òun sì ni Arínú-róde gbogbo n̄ǹkan.”
34:48 Sọ pé: “Dájúdájú Olúwa mi l’Ó ń mú òdodo wá. Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ sì ni.”
34:49 Sọ pé: “Òdodo ti dé. Irọ́ (aṣ-ṣaetọ̄n) kò lè mú n̄ǹkan bẹ, kò sì lè dá n̄ǹkan padà (lẹ́yìn tó ti kú).”
34:50 Sọ pé: “Tí mo bá ṣìnà, mo ṣìnà fún ẹ̀mí ara mi ni. Tí mo bá sì mọ̀nà, nípa ohun tí Olúwa mi fi ránṣẹ́ sì mi ní ìmísí ni. Dájúdájú Òun ni Olùgbọ́, Alásùn-únmọ́ ẹ̀dá.”[1]
34:51 Tí ó bá jẹ́ pé o lè rí (ẹ̀sín wọn ni) nígbà tí ẹ̀rù bá dé bá wọn (ní Ọjọ́ Àjíǹde, o máa rí i pé), kò níí sí ìmóríbọ́ kan (fún wọn). A sì máa gbá wọn mú láti àyè tó súnmọ́.
34:52 Wọn yóò wí pé: “A gbàgbọ́ nínú (al-Ƙur’ān báyìí).” Báwo ni ọwọ́ wọn ṣe lè tẹ ìgbàgbọ́ òdodo láti àyè tó jìnnà (ìyẹn, ọ̀run).”
34:53 Wọ́n kúkú ti ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀ ṣíwájú (nílé ayé). Wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ nípa ìkọ̀kọ̀ láti àyè tó jìnnà (ìyẹn, ilé ayé).
34:54 A sì fi gàgá sí ààrin àwọn àti ohun tí wọ́n ń ṣojú kòkòrò rẹ̀[1] gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe fún àwọn ẹgbẹ́ wọn ní ìṣáájú. Dájúdájú wọ́n wà nínú iyèméjì tó gbópọn (nípa Ọjọ́ Àjíǹde).