107:1
Sọ fún mi nípa ẹni tó ń pe Ọjọ́ Ẹ̀san ní irọ́!
107:2
Ìyẹn ni ẹni tó ń lé ọmọ-òrukàn dànù.
107:3
Kò sì níí gbìyànjú láti bọ́ mẹ̀kúnnù.
107:4
Ègbé ni fún àwọn (mùnááfìkí) tó ń kírun;[1]
107:5
àwọn tó ń gbàgbé láti kírun wọn ní àsìkò rẹ̀;
107:6
àwọn tó ń ṣe ṣekárími;
107:7
àti pé wọ́n ń hánnà ohun èlò (fún àwọn ènìyàn).