al-Masad (المَسَد)

Yoruba:Mikail - Yoruba:Mikail

Chapter 111 • 5 verses • Meccan

← Previous Chapter Next Chapter →
111:1 Ọwọ́ Abu-Lahab méjèèjì ti ṣòfò. Òun náà sì ṣòfò.
111:2 Àwọn dúkìá rẹ̀ àti ohun tí ó ṣe níṣẹ́ (ìyẹn, àwọn ọmọ rẹ̀) kò sì níí rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ (níbi ìyà).
111:3 Ó sì máa wọ inú Iná eléjò fòfò.
111:4 Àti ìyàwó rẹ̀, aláàárù-igi-ìṣẹ́pẹ́ ẹlẹ́gùn-ún, (ó máa wọná).
111:5 Igbà-ọ̀pẹ pọ̀npọ̀nràn máa wà ní ọrùn rẹ̀ (nínú Iná).