110:1
Nígbà tí àrànṣe Allāhu (lórí ọ̀tá ẹ̀sìn) àti ṣíṣí ìlú (Mọ́kkah) bá ṣẹlẹ̀,
110:2
tí o sì rí àwọn ènìyàn tí wọ́n wọnú ẹ̀sìn Allāhu níjọníjọ,
110:3
nítorí náà, ṣe àfọ̀mọ́ àti ẹyìn fún Olúwa rẹ. Kí o sì tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Rẹ̀.[1] Dájúdájú Ó ń jẹ́ Olùgba-ìronúpìwàdà.