al-Qadr (القَدْر)

Yoruba:Mikail - Yoruba:Mikail

Chapter 97 • 5 verses • Meccan

← Previous Chapter Next Chapter →
97:1 Dájúdájú Àwa sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ nínú Òru Abiyì.[1]
97:2 Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Òru Abiyì?
97:3 Òru Abiyì lóore ju ẹgbẹ̀rún oṣù.
97:4 Àwọn mọlāika àti Jibrīl yó sì máa sọ̀kalẹ̀ nínú òru náà pẹ̀lú àṣẹ Olúwa wọn fún gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan.
97:5 Àlàáfíà ni òru náà títí di àsìkò àfẹ̀mọ́júmọ́.